Smiley face

Ogbon Oniroyin 2: Ibere Pepe Ise Iroyin Ati Ipa Awon Olorin Ni Ile Afirika

Bi o tile je wi pe ise iroyin ti dide ni awon ilu oke okun saaju ile adulawo; ohun ti awon ara oke okun si gbagbo gege bi ibere pepe ise iroyin ko papo mo ti ile Afirika rara.

Awon alawo funfun gba wi pe ise iroyin bere lati ori iwe iroyin kiko. Alaye won si ni wi pe eyi bere lati bi fifi iwe ajako ranse, tite ikede sinu takada ati awon iwe kiko atigbadegba.

Eyi rorun latari imo mooko-mooka eleyi to ti rese wale ni awon ilu oke okun saaju ile Adulawo. Awon ohun ti mo salaye saaju ninu "Olorin Loga Oniroyin?" si je ohun ti a le pe ni ibere pepe ise iroyin ni ile Afirika.

Sugbon ohun to joniloju ju ni wi pe, aimoye odun ni awon olorin ibile ile adulawo fi sise iroyin ti awon gan-an ko si fura rara. Awon olorin ile adulawo ka isamulo iroyin sise gege bi okan lara eroja orin lati fi se igbelaruge fun ise orin ti won lasan ni. Lopo igba, won maa n lo isele ayika lati fi se awada, yeye tabi ikilo ninu orin won.

Asiri yii ko lu si awon olorin lowo titi di igba ti awon onise alakada ati onise iwadii fi se afihan ipa won ti a ba n so nipa ise iroyin sise ninu orin kiko ile adulawo. Ni awon akoko yii, ise iroyin gan-an ti lale wu.

Iwe iroyin akoko lagbaye ti n je "Relation aller Fürnemmen und gedenckwürdigen" jade ni odun 1605 eleyii ti won fi ede Jamani ko. Leyin eyi ni awon ilu mii loke okun bi Holland, Spain ati France naa bere si gunle gbigbe iwe iroyin jade.

Ni ile Afirika, orileede Mauritius ni iwe iroyin ti koko jade ni odun 1773 eleyii ti won fi ede faranse gbe jade.

Leyin naa lati ri eyi to jade ni Cape Town lodun 1800.

Iwe iroyin Al-Waqa'i'a al-Masriya eleyii ti a fi ede arabic ko jade lodun 1828 ni ilu Cairo to wa ni Ijibiiti.

Ni ilu Nigeria, iwe iroyin akoko ni won pe ni "Iwe Irohin Fun Awon Ara Egba" eleyii to jade ni odun 1859 ni ilu Abeokuta. Ede Yoruba ati Geesi ni won fi gbe iwe iroyin naa jade eleyii to n jade lose meji-meji. Eni-owo Henry Townsend to je okan lara awon ajihinrere C.M.S lo se agbeteru iwe iroyin naa.

Nigbogbo akoko yii, bi igba ti ko si iwe iroyin rara lojo ni ile adulawo. Latari oju dudu ati aimooko-mooka to gbile ni akoko naa.

Pupo iroyin to te awon eniyan lowo lo je eyi to ti odo awon olorin jade ati eyi ti awon eniyan feti ko laaarin oja nla ati awon ibudo mii.

Awon Yoruba bo, won ni aimu eran dele ologini ni ko je ki awon eniyan mo wi pe ode gidi nii se. Awon olorin ibile kopa to joju ninu ise iroyin nipa wi pe won ko je ki eti ara ilu di, sugbon pupo won ni ko ni oye ohun ti won se ni awon akoko naa.

@OlayemiOniroyin, sebi ti ito ko ba tan lenu, eje kii tan leekanna. Alaye mi ko ti tan.

E ku Ikale!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment