Davido omo baba olowo to gba ami eye okunrin olorin to dara ju ni ile Afirika lodun to koja lo tun gba ti odun yii nigba ti Yemi Alade tewo gba ti abala olorin obirin to dara ju ni ile Afirika.
Bakan naa, DoroBucci lo tun gba orin to dara ju lo fun odun 2015 eleyii ti awon omo olorin Mavin gbe jade pelu atileyin Don Jazzy to je baba isale won.
Eyi to tu ja gbogbo irawo tun ni bi awon omo ibeji 'oran' olorin ile Nigeria, Peteru ati Poolu omo Okoye (P-square) se gba ami eyi egbe olorin to laamilaka julo fun odun 2015.
Lara awon omo Naija ti won tun ri nnkan gba wale ni Patoranking, D'banj Eje Nla ati Burna Boy.
Lafikun, Ayodeji Ibrahin Balogun ti gbogbo eniyan mo si Wizkid ko ri ohunkohun gba wale loteyii. Bi omo naa se lo bee lo se pada pelu 'notin' lati ilu South Africa.
Bi won se gba ami eye naa ni yii labala-labala:
Best Female: Yemi Alade (Nigeria)
Best Male: Davido (Nigeria)
Best Group: P-Square (Nigeria)
Best New Act Transformed by Absolut: Patoranking (Nigeria)
Best Hip Hop: Cassper Nyovest (South Africa)
Best Collaboration: AKA, Burna Boy, Da LES & JR: "All Eyes On Me" (SA/Nigeria)
Song of the Year: Mavins: "Dorobucci" (Nigeria)
Best Live: Diamond Platnumz (Tanzania)
Video of the Year: "Nafukwa" – Riky Rick; Director: Adriaan Louw
Best Pop & Alternative: Jeremy Loops (South Africa)
Best Francophone: DJ Arafat (Ivory Coast)
Best Lusophone: Ary (Angola)
Personality of the Year: Trevor Noah (South Africa)
MAMA Evolution: D'Banj (Nigeria)
Best International: Nicki Minaj
Artist of the Decade: P-Square
MTV Base Leadership Award: Saran Kaba Jones & S'Bu Mavundla
To ba je torin, ohun to daju ni wi pe mi o lohun orin gidi; to ba je tilu, emi o mo bi won se n fi kongo kanju awo ilu atata. Sugbon to ba je ti iroyin to gbamuse, awon iroyin to ta, to dun bi sikin ti won yi lata ki won to yan-an lori ina, @OlayemiOniroyin ni ke e maa tele nibi ajulowo iroyin ti gbe n kun yunmuyunmu bi ina elentiriki.
E ku ikale!
0 comments:
Post a Comment