Sebi iponju ati aibikita awon asaaju ile Nigeria lo je o dabi eni wi pe olopolo dudu ni gbogbo awon eniyan dudu.
Aimoye ebun ati ogbon atinuda ni Edua oke fi da wa lola, iponju ati aibale okan lo je o dabi eni wi pe olopolo dudu ni gbogbo awon eniyan dudu.
Anfaani lati se afihan ogbon ori lasan ni awon ewe iwoyii n beere ati iranlowo gege bi ironilagbara ko ma ba dabi wi pe olopolo dudu ni gbogbo awon eniyan dudu.
Ti awon ijoba ba se eyi, orisirisi ise iyanu ni o maa ti ilu wa jade, ti ilu Nigeria yoo si wa lara awon ilu alagbara julo lagbaye.
Nibayii, okan ninu awon omo Nigeria ti yi masiini okada pada si oko ofurufu baalu.
Ti iru eni bayii ba ri iranlowo owo, imo ati igbelaruge to muna doko, ipo wo le lero wi pe yoo wa lagbaye?
Lara ohun ti mo feran julo laye ni ilu mi, Nigeria. Nigeria ilu ogo, iyi ati ola. Ilu to n san fun wara ati oyin. Ilu awon olododo eniyan ati asaaju rere. Ilu awon eniyan mimo ati onilaakaye repete.
Ki Oluwa bukun ile Nigeria!
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment