Smiley face

Ogbon Oniroyin 3: Imo Ero Lo Gbe Agbara Fun Awon Olorin

Lara ohun to fa ifaseyin fun idagbasoke iwe iroyin nikete ti idasile re wo ile adulawo ko tayo aimooko-mooka to wopo laaarin awon eniyan dudu.

Akitiyan awon to n se agbateru eko mooko-mooka nigba naa lo je awon ajinhinrere ti won kede esin kristeni.

Erogba won lori eko mooko-mooka ti won mu wole nigba naa ni lati ran awon eniyan dudu lowo lati le ka bibeli mimo.

Iwe iroyin akoko to jade ni ile Nigeria lodun 1859 eleyii ti won pe ni " Iwe Irohin" ko lo ju odun mejo lo lori ate ko to pada kogba wole odun 1867 ni ilu Abeokuta.

Eleyii mu pu agbara iroyin wa lowo awon olorin ju awon oniroyin lo. Awon eniyan ko tile gba wi pe awon oniroyin wa.

Nipa agbara ero igbalode, ogbon atinuda, ati ewa ise ona orin tun bo mu orin wayami ninu agbara ti a ba n so nipa ise iroyin sise.

Leyin igba ti iwe iroyin tun ti pada ji dide, ti imo ero si ti tesiwaju nipa telifisan ati redio, sibesibe agbara ise iroyin sise si wa lowo awon olorin ibile.

Aimoye awon egbe, onisowo ati ijoba maa n lo awon olorin lati se ipolowo tabi gbe ero won saye. Iru awon nnkan ipolowo bayii si maa n wa titi latari imo ero to ti gberu, eleyii to n mu awon olorin maa ka orin sinu rekoodu.

Ohunkohun to le wa ninu iwe iroyin, leyin ose meji si osu meji ti iroyin naa ti jade ko tun ni si lode mo. Sugbon eyi ko ribe ti a ba n so nipa orin kiko, paapa julo orin ti won ka si ori rekoodu. Pupu awon olorin taye n fe bi Ayinla Omowura ma n ba awon eniyan se igberaluge ati ipolowo oja ninu orin won.

Sugbon laye ode oni, nnkan tun ti yi pada...
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment