Ti ina ko ba tan laso, eje kii tan leekanna, Aare Muhammadu Buhari ti fesi lori abajade ile ise olopa nipa iwe ofin ilana ati agbekale ile igbimo asofin agba ti awon kan lo yi pada leyin.
Oluranlowo nipa eka iroyin fun Aare Muhammadu Buhari, Garba Shehu ti so wi pe Aare Buhari ko ni di eka eto awon onidajo lowo lori ise won lati se ohun to ba ye nipa awon ti oro naa ba ja le lori.
Iwadii ti awon ile ise olopa fi ranse si aare eleyii to foju han gbangba wi pe won yi ofin ilana ile igbimo asofin eleyii to fi anfaani sile fun Bukola Saraki lati di aare ile igbimo asofin agba lojo kesan-an osu kefa odun.
Bi o tile je wi pe ko ti si aridaju boya esi iwadii naa ti de odo awon eka onidajo ile yii, sugbon ohun ti a gbo ni wi pe awon apa kan omo ile igbimo asofin ti won n se olooto si Ahmad Lawal, eni ti egbe APC fe ko wa ni ipo aare ile igbimo asofin agba, ti gba Saraki ati igbakeji re niyanju lati kowe fi ipo sile ko to di wi pe nnkan buruju bayii lo fun won.
Okan ninu awon amofin agba ile Nigeria, Amofin Norrison Quakers (SAN) so wi pe yiyi iwe ofin je ese nla eleyii ti ijiya re je ewon gidi, eto idajo si gbogbo sise owo re bo ti to ati bo ti ye.
Lori oro yii kan naa ni Bukola Saraki ti soro le lori, oro yii lo so lati enu oluranlowo re nipa iroyin ati ikede, Yusuph Olaniyonu.
Saraki ni aheso oro lasan ni gbogbo awuyewuye ti won so kiri nigboro aye, awon oro naa ko si lese n le rara. O ni awon oro yii ko ye ko je ninu iroyin nikan ni yoo mo, o si pe awon akegbe re nija lati pada re nile igbimo asofin ki awon jo te pepe oro naa to ba je looto nigbogbo esun ti won fi kan-an.
Awon omo ile igbimo asofin agba ile Nigeria yoo maa pade lola ode yii (28-07-2015) ni ile igbimo asofin agba to wa ni ilu Abuja.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment