Smiley face

Ẹ má gbàgbé Oyin Adejobi

Oyin Adejobi

      A kì í mọ̀ọ́ rìn kórí má mì. A kò le sọ ní sàn-ánsàn-án wí pé àwọn oǹkọ̀tàn ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kò ṣeun tó tàbí wọn ṣe àṣìṣe. Sùgbọ́n ènìyàn kì í mọ̀ọ́ gún mọ̀ọ́ tẹ̀ kí iyán ewùrà ó má ní kókó. Kò sí ènìyàn tí yóò wẹdò tí ò ní fomi kanra.



Rev. Ajayi Crowther ṣisé ribiribi nipa akiyan bi Yorùbá ṣe di kíkọ sílẹ̀, pàápàá jùlọ ṣíse atúnmọ̀ bibeli lati inu ede Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá. Bákan náà ni a ri àwọn ènìyàn bi Henry Townsend, Hanna Khiram ati bee bee lo eleyii ti won se gudugudu-meje yaya-mefa.

Sùgbọ́n ṣá, a kò sàì rí kùdìẹ̀kudiẹ nínú àwọn iṣé àwọn ẹni sáájú eléyìí  tí àtúnṣe kò ti débá di òníolònìí yìí. Lára àwọn àkùdé náà ni bí wọn ṣe túnmọ̀ Sátánì inú bíbélì gẹgẹ bí Èṣù. Gege bi ìgbàgbó Yorùbá, ìtàn Sàtánì inú bíbílè ko fara pe ti  Èṣù tó jẹ́ òrìṣà kan pàtàkì nílẹ̀ Yorùbá.

Ohun ti mo fẹ sọrọ ba gan-an ko leyii, ayaba lasan ni. Ohun to tun jọ bi eleyii ni bi awon onise alakada ko se fi gbogbo ara kobi ara si Oyin Adejobi gege bi ipile ere onise ile Yoruba. Gege bi Ojogbon Philip Adedotun Ogundeji ti ọgba ileewe Yunifasi Ibadan se so, o ni boya nipa ailera re gege bi abarapa lo mu eleyii wa. [Oyin Adejobi je akanda eleyii ti ko le fi ẹsẹ rẹ mejeeji rin lai lo igi tabi kẹkẹ] Sùgbọ́n oun gba wi pe, ipò abarapa yii gan-an lo yẹ ko mu awon eniyan ji gìrì si iṣẹ rẹ. Gege bi abarapa, akitiyan tabi ipa re ninu igbedide ere onise igbalode ko fẹ ẹ yato si ti awon akẹgbẹ rẹ bi Duro Ladipo ati Kola Ogunmola ti won jọ wa lati ilu Òsogbo.
Sùgbọ́n màá gbìyànjú lati fenu ba téétèèté nípa igbe ayé rẹ̀ àti àwọn ipa tó kó lórí ìtàgé. 

Ẹ jẹ ka tibi pẹlẹbẹ mu ọ̀ọ̀lẹ̀ jẹ, P.A Ogundeji ni dun 1930 ni won bi Joseph Oyinlola Adejobi ni ilu Osogbo, Wikipedia ayelujara ni odun 1926 ni won bí i. Oruko baba re ni Osunleru Akanni Adejobi eni to pada yii oruko si Simeon nigba to di atunbi ninu Kristi Olugbala. Nigba ti oruko iya rẹ si n jẹ Esther Ọmọrinọla Adejobi. Iyawo merin lo fẹ, bẹẹ lo si bi ọpọlọpọ ọmọ. Oruko awon iyawo rẹ ni Grace (Iya Osogbo), Emily, Margaret ati Kuburat, gbogbo àwọn wọ̀nyìí naa ni wọn si n jọ n ṣiṣẹ pọ ninu ẹgbẹ tíátà Oyin Adejobi.

Àlàyé ṣì ń tèsìwájú…
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment