Smiley face

Eleyii Yoo Se O Ni Anfaani Gidigidi: Oro Agbara Lati Ori Ite Mimo

Ninu iwe Romu 10:13, bibeli so wi pe, "Enikeni to ba ke pe oruko Oluwa ni a o gbala."
Awon oro meji kan wa ninu ese bibeli yii ti mo feran julo.


Ikinni ni "Enikeni". Enikeni tun mo si enikeni, ki ba a se keferi, apaayan, asewo, ole, elese paraku, eniyan dudu tabi funfun, omode tabi agbalagba, elesin kristeni abi eni ti kii se esin kristeni.
Ohun ti oro Oluwa so ni wi pe enikeni to ba ke pe oruko Oluwa a o gbaa la.
Oro keji ni "Gbala." Ibeere mi ni, "igbala lowo kini?"


Bibeli so wi pe enikeni to ba ke pe oruko Oluwa ni a o gbala. Ti a ba n soro igbala, opolopo a maa ro nipa igbala lowo orun apaadi tabi iku ayeraye nikan. 


Iru igbala ti oro Olorun n so nibi tobi gan-an, eleyii to koja igbala lowo iku ayeraye nikan.
O n soro nipa igbala ni gbogbo ona yowu ti eda ti le ba ara re. John 8:36 so wi pe, eni ti Omo Olorun ba so di ominira yoo di ominira nitooto. Eleyii n so nipa ominira ni gbogbo igbe aye eda.
Iru Ipo wo lo wa ti o fe ki Oluwa gba o la, se iponju ni, aisan, airi ise se, airi omo bi tabi ijakule?
Oro Olorun so wi pe ti o ba le ke pe oruko Oluwa, a o gba o la ( a o so o di ominira nitooto).

Bibile tun so wi pe, Olorun feran araye to bee gee, eleyii to fi omo bibi inu re kan soso fun wa. Enikeni to ba gbaagbo yoo ni iye ainipekun. (A le ri eleyii ni John 3:16)


Ede Giriki ati Heberu ni won fi koko ko bibeli ki won to yi si geesi ati Yoruba.
Ohun ti ede Geesi yii si "everlasting life" eleyii ti Yoruba yii si "iye ainipekun" je Zoe ninu ede Giriki ti won fi koko ko bibeli. 


Itunmo Zoe ninu ede giriki ni IYE, iru iye ti Olorun oga ogo ni fun ara re tabi iru iye ti Olorun n lo.
Zoe rekoja iye ainipekun tabi everlasting life gege bi giriki se tunmo re. Zoe ni orisi iye ti Olorun Baba fun rare n lo - ohun to fi n je Olorun alagbara.


(Mo fe ko o duro, ki o ronu si ohun ti mo so keyin ki o to tesiwaju. O si tun le tun abala naa ka sii)
Eleyii tayo oye eniyan lasan, yoo si soro fun opolo isiro eniyan lati gba iru oro yii gege bi ododo, sugbon bo se ri gele ni yen.

Bi o tile je wi pe "iye ainipekun tabi "everlasting life" wa lara Zoe sugbon ko se akotan itunmo Zoe patapata. Eleyii si waye nipa isoro to wa ninu sise idako ede kan si ede miiran.

Zoe ni iwe mimo se ileri wi pe a o fun wa lati gba wa la lowo orun apaadi ati gbogbo ise owo re bi aisan, iponju, ibanuje, ese ati ipayinkeke.


Sugbon ki eniyan to le di eni igbala, eniyan ni lati kepe oruko Oluwa nipa igbagbo ninu iku ati ajinde Jesu ati jijewo re gege bi Oluwa ati Olugbala. Eleyii se pataki gidigidi.
Bibile so wi pe nipa eleyii, a o gba wa la.

A ko fun wa ni Zoe lati ni iye ainipekun nikan sugbon lati fun wa ni iye nipa gbogbo ohun to nii se pelu igbe aye wa pata.

Ti o ba ni Zoe ninu, ko ye ki oju re maa rare tabi ki o ma le ohun kan fun igba pipe lai ma ba. Ko ye ko ri bee. Oro Olorun so ni 1 John 4:17 wi pe, bi Olorun se je ni orun bee gele ni awa naa je ni aye. Sugbon ti o ko ba ni oye awon nnkan won yii, o ko le gbe igbe aye to ye ko gbe gege bi eni to ni iye Olorun (Zoe) ninu.

Bibeli so wi pe, mo le se ohun gbogbo nipase Kristi ti n gbe inu mi. Bi awon ota tile yo si mi ni ona kan soso, egberun ona ni won yoo gba salo pada nitori Emi Olorun mbe pelu mi. 


Olorun so wi pe, ori apata ni oun yoo ko ijo oun le, orun apaadi kii yoo si lagbara lori re. Nitori ati fun mi ni kokoro ijoba orun, ohunkohun ti mo ba de laye, o ti di dide lorun; ohunkohun ti mo ba tu laye ti di titu lorun.
Ohun gbogbo n sise papo fun ire fun mi. Mo n soro ologbon jade nigbogbo igba, nitori ati so kristi di ogbon fun mi. Mo n rin ninu ogbon, mo n rin ninu agbara, mo n rin ninu ogo. 

Bibeli so wi pe, oju ona olododo kun fun imole nla, eleyii to n mole sii ni gbogbo ojo. Okunkun ko le bori imole mi. Bibeli so wi pe ati mu mi jade kuro ninu okunkun bo sinu imole. Fun idi eyi, ijoba okunkun ko lagbara lori mi mo. 

Mo ju asegun lo. Nitori eni to n gbe inu mi ju eni to n gbe inu aye lo. Ati fun mi ni agbara lati te ejo ati akeeke mole, won ki yoo se ipalara fun mi. Mo dabi oke ti a ko le si nidi. Ti enikeni ba fori so mi, yoo fo yangayangan. 


Awon eniyan n fi ire wa mi ri, nitori ati fi ami ororo yan mi fun ire. Bibeli so wi pe oruko Oluwa, ile iso agbara ni. Olododo sa wo inu re o si ye. Nje mo di eni iye lonii ni oruko Jesu.
Gege bi (Psalm 116:10) se so, mo gbagbo, fun idi eleyii mo so jade wi pe ona mi bere si ni la. Awon angeli Oluwa jade lo lati la ona fun mi. Oluwa n pese fun aini mi. Mo ni opolopo lati fifun awon orileede.

Oro Oluwa so wi pe, eni to ba ke pe Oluwa, a o gba a la, ni Oruko Jesu mo di eni igbala lonii, a gba mi la lowo iku ati iponju, agba mi la lowo ese, a gba mi la lowo airina-airilo. Igbe aye mi bere si ni dara ju ateyin wa lo nitori emi iye olorun oga ogo n gbe inu mi. Amin
@OlayemiOniroyin






























Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment