Smiley face

Kaabo Sinu Osu Ayo Re

 Ohun to ti n sele seyin tabi sele lowolowo ko ni ohunkohun se pelu ohun ti yoo tun pada sele.

Eru ana le di oba lonii; eni ti aye si ti gbagbe re le di apesin bi oosa ajiki.


Ti Fayose ko ba so wi pe oun ti wa Danfo ri, nje iwo mo? Won ti fi igba kan dajo iku fun Obasanjo ri ko to wa joba. Sanmoni le lo tinrin lonii, kurukuru le bo oju orun, okunkun sile su bole, sugbon ma se so igbagbo re nu.


Ipalara tabi akoba to le se si igbe aye re ni lati so ireti nu. Ojo ti igbagbo ati ireti ba ti sonu ni eniyan di oku patapata.

Mu okan re le bi okuta, je akinkanju bi jagunjagun, si ma je ko re o ninu igbiyanju re. Ti emi ba si wa, ireti si mbe.

Ohun to ga bi oke Olumo niwaju eniyan, bintin ni niwaju Olorun oga ogo to da aye ati orun. Oba oke yoo so ibanuje re di ayo, yoo si so ekun re di erin. Oba oke yoo so agbegbe re di nila, a o mu o joko laaarin awon oba, ayo yoo si kun ayo re. Osu yii gan-an ni osu ayo re to ti n reti.

Kaabo sinu osu ayo re!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment