Leyin iroyin to jade nipa bi Ooni Alayeluwa Oba Okunade Sijuwade se gbese lo ree ba awon babanla re, ta a si tun ri awon eniyan pataki lawujo bi Aare ana, Goodluck Jonathan se fi ibanikedun re ranse si idile oba naa, sibesibe awon oloye Ooni Ile Ife tako iroyin naa wi pe iro lasan ni.
Won ni Ooni mbe laye ati laaye idera, koda, won ni baba n mura eto igbeyawo omo re ti o waye ni opin ose ti n bo yii.
Sugbon gege bi okan lara awon oloye, eni to ko lati je ki won daruko oun, se so.
"Nipa iru eni ti Ooni je, yoo soro lati kede ipapoda re lai je wi pe won se awon etutu kan gege bi agbekale isese Yoruba ati lati daabo bo awon idile oba to gbese.
Eni naa tun so siwaju,
"Obalufe ti Ile Ife ati okan lara awon afobaje, Oba Folorunso Omisakin nikan lo lase ati kede ti oba ba waja.
Eni yii nikan lo lase lati se bee, ti eni naa ko ba wa ti so ohunkohun, kosi ohun to jo wi pe oba waja.
"Yato si eyi, won ko gbodo kede ipapoda oba a fi ti idile oba to waja ba wa ko gbogbo eru won to wa laafin ayafi ti won ba fe padanu awon dukia naa. Nitori wi pe nikete ti Obalufe ba kede ipapoda oba enikeni ko ni le mu ohunkohun jade mo."
A tun rigbo wi pe nikete ti Obalufe ba kede wi pe oba waja, ojo meje ni won yoo fi ti gbogbo oja to wa ni ilu Ile Ife pa ati wi pe gbogbo igi ni won yoo ma ge lule lati fi jeri si wi pe oba ti lo re ba awon babanla re looto.
To ba je wi pe laye atijo ni, ohun to seese ni wi pe ki iru iroyin bayii ma ti de owo ara ilu. Sugbon nipase olaju, imo-ero igbalode, ati ise iroyin sise to ti bureke, awon nnkan bayii soro lati pamo fun ara ilu.
@OlayemiOniroyin
0 comments:
Post a Comment