Sii Olayemi Oniroyin,
Mo koko fe dupe lowo gbogbo eyin ololufe Olayemi Oniroyin ti e n ba mi ka awon leta mi ti won ba mi te jade fun kika.
Maa gbiyanju nipa gbogbo agbara ti Olorun Oba fun mi lati ko gbogbo ohun to sele si mi pata fun awon eniyan lati le fi kogbon. Awon Yoruba so wi pe eni to jin si koto, o ko ara yoku logbon ni. Pupo awon ohun to sele si mi ninu igbesi aye mi ni ko ba ti ma waye to ba je wi pe iya mi o fi mi soko sibi ti oju re ko ti ni to mi.
Bi o tile je wi pe won wa igbe aye to dara fun mi ni won se ni ki n ma lo s'Eko, sibesibe igbe aye ti mo n gbe nibe ko han si awon obi mi. Iya mi ko wa wo mi l'Eko tabi ko tile wadii lati mo nipa ohun to n sele si mi titi ti idaamu fi de.
Eko nla si ni eyi je fun awon obi pata, e sora lati maa fi awon omo yin fun awon eniyan nibi ti oju yin ko ti ni gbe to won.
Ko seeyan mo, eniyan won.
Laipe yii ni mo ka iroyin nipa okan lara awon oluko ile eko University of Lagos to fi ipa ba omobirin kan lajosepo ninu ofiisi re. Omo yii n gbiyanju lati wo University of Lagos sugbon maaki re ko kun to fun won lati gba a. Baba omo naa ranti wi pe okan lara awon oluko ile iwe naa n gbe ladugbo, o si too lo boya o le ni iranlowo to le se fun omo re. Oluko naa se ileri wi pe oun o ran won lowo. Okan baba omo ba bale pese.
Ninu iwe Iroyin Punch to jade lojo kefa, osu kejo odun 2015: Oruko oluko naa ti won da ni Afeez Baruwa nigba ti omo to fa idi re ya je omo odun mejidinlogun (18). Ojo ketalelogun osu keje ni isele naa waye nigba ti owo awon olopaa te okunrin naa lojo keta osu kejo odun 2015.
Lojo ti o se ise ibi naa, o so fun awon obi omo naa wi pe ki won fi omo won sowo si oun ni nnkan bi aago merun-aabo idaji nitori oun fe ji lo si ile iwe lojo naa ni.
Oluko yii mo wi pe opo awon eniyan ni ko le ti i de ni akoko naa lofiisi oun, eleyii o fun lanfaani lati se ohun to fe se.
O se omo naa sakasaka to je wi pe gbogbo isale ikun lo n dun omo naa. Bi o tile je wi pe omo naa ko fe jewo ohun to sele sii, sugbon ailera lo je ki asiri tu. Olorun nikan lo mo iru ohun to ti bo omo naa nidi ti isale ikun fi n dun omoolomo.
Ju gbogbo re lo, awon obi omo naa ni emi ri bawi ju.
Iru eyi to tun jo iru re ni eyi ti mo ri ninu fiimu October 1 eleyii ti Kunle Afolayan gbe jade. Awon ara ilu fi awon omo won ranse si ilu nla labe isakoso alagba ijo, eniyan Olorun.
Sugbon o je ohun ijoloju lati ri wi pe alagba ijo n ni ibasepo okunrin si okunrin pelu awon omo ti won ko fun un, eleyii to se ileri fun awon obi omo naa wi pe oun yoo ran won lowo lati ran won lo si ile eko ni ilu nla.
Ogbe okan ayeraye ati ibanuje lo je fun awon omo okunrin ti won gbe lodo alagba ijo eleyii to ko kuro lati abule wa si ilu nla.
Ohun ti alagba so fun awon obi won ni wi pe iranlowo eko ofee ni oun fe se fun awon omo naa, eleyii to je wi pe n se ni i ba won sun bi aja.
Ko si eni ti eniyan le gbagbo mo. Ile aye ti dorikodo. Ma si ro awon obi pe ki won fi isele igbe aye mi se arikogbon. E yee fi awon omo yin soko sibi ti oju yin ko ni i to, o lewu.
Se eranti wi pe anti mi to wa mu ni nile wa kii se anti mi gan-angan, okan ninu awon omo egbo moomi niise. Bi o tile je wi pe bee naa lo ri, se omo egbon moomi kii se anti mi mo ni? Abi eru tun le maa ba awon moomi lati je ki n tele lo s'Eko.
Mi o le so boya anti mi lowo nipa isele to sele si mi tabi kii se ajomo ohun ati oko re.
Nigba ti mo ba pari alaye mi, ohun ti e ko mo le e mo pata.
Gbogbo ohun to sele pata ni mo se ileri lati ko jade kee le fi kogbon nipa ibi ti aye de. Ika ni eniyan, o daju si laye.
Ohun kan se Pataki ti mo fe fi to yin leti ko to di wi pe in maa se itesiwaju ninu awon leta mi to ku ni kiko.
Awon ohun to sele si mi leyin igba ti mo wo ile babalawo, leyin ti eje ti bere si ni jade lara mi ti oko anti mi si ti n fi ori gbaa ni ko soju mi mo.
Nitori mi o mo ibi ti mo wa mo ni gbogbo akoko naa, gbogbo ohun to si n sele si mi ni mi o mo rara.
Sugbon nipa awon eri to jade, alaye awon olopaa (oro naa pada di oro olopaa), ati ohun ti mo fi oye mi gbe ni awon alaye mi to ku gunle.
Awon Yoruba ni eni a gbe iyawo bo wa ba, kii gbe ori iganna woran. Ki lo sele leyin igba ti eje bere si ni da lara mi si ori oko anti mi?
Nje ogun owo to fe fi emi ati oyun inu mi se pada je?
Ki lo sele si mi, ki lo sele si oyun inu mi?
Kini ohun to sele si baba alawo oloogun ika ti won gbe ise fun?
Bawo ni asiri oko anti mi se pada tu?
Gbogbo alaye le o gbo pata.
E ku oju lona?
Emi Ni Ti Yin Ni Tooto,
Morufa Eko

0 comments:
Post a Comment