Bimbo Thomas |
Ti a ba n so nipa ise tiata ile Naijeria, Bimbo Thomas ti kuro ni ojewewe ti won nawo juwe re. Lara awon fiimu to ti kopa ribiribi ni eleyii ti Funke Akindele gbe jade ti won pe akole re ni OMO GHETTO, nibi to ti kopa Nikky.
Gege bi alaye ti Bimbo se fun awon oniroyin iwe iroyin Vanguard ti ile Nigeria, o ni fiimu OMO GHETTO fe e je fiimu to gbo oun ju lo nitori eda-itan ti oun kopa re jina si iru igbe aye ti oun gbe loju aye.
Ninu fiimu yii lati ri Nikky nibi to ti n faraki, to si n je ko maa ye won pe oun ni Iyanlaya awon omo ghetto. Yato si eyi, omobirin naa n pago mole, won si fa surutu kiri igboro pelu awon akegbe re ninu ere naa.
Lara ohun to tun jeyo ninu iforowero Bimbo Thomas ati awon oniroyin ni ile itaja re, Bimbally, nibi to ti n ta awon orisirisi oti waini to gbamuse. Ninu ero omobirin naa ni lati ni eka kaakiri; o si tun se afikun ife re lati maa ta awon aso oge pelu.
Omobirin to kawe gboye ni Ifafiti ijoba apapo to wa niluu Eko ko sai menu ba bo se bere ise tiata.
O se lalaye wi pe Tayo Odueke ti gbogbo eniyan mo si Sikiratu Sindodo, eni to ti bere ise tiata saaju re, lo gba a niyanju lati dara po mo ise tiata nigba to ri ipa re nidi ise akanse ti won se ni ile iwe. ( Ise ona alatinuda, Creative Art, ni Bimbo Thomas ka gboye akoko ni Ile iwe Unilag).
Ohun ti Bimbo so nipa Sikiratu Sindodo ni yii:
"O gba mi nimoran wi pe ki n maa bo ninu ise fiimu niwon igba to je wi pe mo ni gbogbo amuye bi karisima ati awon nnkan mi-in"
Ohun to dun mi ju ti oniroyin Vanguard ko beere lowo Bimbo ni nnkan ti osere naa ni lokan pelu gbolohun to so gbeyin: "... awon nnkan mi-in".
Niwon igba ti eleyii ko ti jeyo ninu iforowero won, ninu ero mi, o ni lati je ewa ti omobirin naa ni lohun to o n soro o ba. Awon Yoruba ni funfun niyi ehin, Sunny Ade si fi tie kun wi pe: "Omu sikisiki niyi obirin". Atiwaju ateyin Bimbo ko ja kereemi ti eniyan le foju pare.
Bimbo dudu, dudu ohun o jona, didan nii dan bi korosin.
Lopin ohun gbogbo, Bimbo Thomas ko sai menu ba oserekunrin to je dodo re julo lagbo amuludun. John Dumelo omo ilu Ghana ni Bimbo ni oun gba dun swaga re ju lo. O ni didun inu oun ni yoo si je ti ise ba jo pa awon po lori itage, ti awon si ni anfaani lati jete,kiisi tabi ki won jijo pon enu ara won la.
0 comments:
Post a Comment