Igbeyawo Olusegun Obasanjo pelu iya Iyabo, Oluremi Obasanjo ni yii lodun 1963.
Oluremi ni obirin akoko ti Obasanjo Aremu fe, eto igbeyawo won si waye lojo kejilelogun osu kefa odun 1963 ni Camberwell Green Registry, South East London.
Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, omo odun mokanlelogun ni Oluremi lodun ti Ebora Owu fi oruka si i lowo loju ebi ati ojulumo.
Awon Yoruba ni won kii ka omo fun olomo, Olayemi Oniroyin naa ko si ni ka iye omo ti Obasanjo bi, sugbon gege bi akosile to daju se so, omo mokanlelogun (21) ni Olusegun Mathew Okikiola Aremu Obasanjo bi, mefa pere si ni Oluremi bi fun un ninu won.
Awon omo ti Oluremi bi fun naa ni:
Senator Iyabo Obasanjo, Busola Obasanjo, Olusegun Obasanjo (akobi omo re okunrin).
Awon yoku ni Olugbenga Obasanjo, Enitan Obasanjo ati Damilola Obasanjo.
Ninu iwe Itan-ara-eni ti Obasanjo gbe jade, "My Watch", Obasanjo se afihan Oluremi gege bi iyawo to ti jawe fun (iyawo to ko sile ni kootu). Sugbon alaye Oluremi ko ba ti Obasanjo dogba.
Kini Oluremi so nipa igbeyawo re pelu Obasanjo?
E pade mi ninu abala keji iroyin yii ti mo pe akole re ni "Ohun Ti E Ko Mo Nipa Igbeyawo Obasanjo Ati Iyawo Re, Mama Iyabo (2)."
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment