#Ogulutu #6
Ki n to so die fun yin lara itan igbesi aye mi kan ti mi o le gbagbe laelae. Se e ko gbagbe alaye ti mo se fun yin lose to koja? Lara ona ti eniyan le fi se se awari talenti to ni ni nipa sise akiyesi si awon ohun ti okan eni n fa si ju lo, awon ohun ti maa n dani lorun bi egbin, awon nnkan ti maa n fun ni nisipaya, iwuri tabi koriya, itara tabi awon nnkan ti maa mu ara eni bu maso lopo igba. Awon ohun to jeni logun julo ati ohun to maa n wu ni i se tun je apeere pataki ti a ko gbodo foju pare.

Ilu Ibadan ni won bi mi si, ibe naa ni mo si dagba si. Ileewe
Jericho High School to wa ni Eleyele niluu Ibadan naa ni mo ti ka iwe mewaa mi
pe lodindi. Ni awon akoko ti mo wa ni ileewe girama, mo nife iran ere boolu
wiwo pupo to fi je wi pe mo fi aseju kun-un. Ti won ba na Super Eagles mi o ki
n le jeun, inu mi a baje bi eni ofo se, omi ekun yoo si maa da loju mi poroporo.
Aimoye igba ni mo maa n sa kuro nileewe lati lo woran ere boolu Shooting Stars
ni papa-isere Lekan Salami to wa l’Adamasingba, ni awon akoko ti ere boolu
liigi Naijiria ba bo si aarin ose. Bakan naa, ko si ere boolu ti won gba ni
awon ilu okeere bi liigi Premier ti ko ye mi yekeyeke.
Ife boolu yii wo mi lokan to bee gee to je wi pe mo bere si
ni ri ara mi gege bi agbaboolu. Yato si awon boolu alagbole ti mo ti n gba
tele. Mo pinnu lati darapo mo egbe agbaboolu kan ti won maa n sedaraya ninu
ileewe Oba Akinbiyi High School to wa loju ona Mokola-Oremeji. Mo ti bere si n
ri ara mi gege bi okan lara awon agbaboolu ile okeere nla. Mo n ro wi pe laipe
ni irawo mi yoo yo loke, maa si dapesin kari aye. Awon eniyan yoo maa pon mi le,
maa lowo bi elewu etu, maa si ra moto jo bi isu.
Leyin ose kan ti mo bere, o ti bere si ni su mi, o ti n re
mi. Ko kuku je wi pe boya ni mo ti moo gba, mo kan an tiraka naa ni. Yato si
eleyii, ohun ti mo lero ko ni mo ba. Inira gbaa lo je fun mi, mo tiraka lati lo
lose keji. Sugbon ose keta re ni won o ri mi mo.
Leyinoreyin lo ye mi kedere wi pe boolu gbigba ki i se ebun
mi. Oju kokoro lo sun mi debe. Owo, okiki, iyi ati ogo to ro mo awon irawo
agbaboolu gan-an lo je ki boolu wu mi gba. Eleyii to si je asise ti opolopo n
se laye ode oni.
Boya ki n tun beere ibeere naa leekansi: kin ni awon ohun ti e
maa n fe lati se bi won ko tile ni fun yin ni kobo nidi re? Idahun ibeere yii
lo le se afihan ojulowo ebun te e ni.
Afikun, ohun naa gbodo je ohun ti yoo ro yin lorun ni sise.
Bi o tile nira fun awon kan, awon ti won lebun naa ko ni ri bi inira rara. Maa
duro nibi, sugbon mi o ti pari alaye mi. O di gba.
0 comments:
Post a Comment