Smiley face

Eto idibo gomina ipinle Kogi di fopomoyo

Faleke ati oloogbe Abubakar Audu
Eto idibo gomina ipinle Kogi di fopomoyo
*Faleke n binu, ara ilu n sofo
*Iwe ofin ruju mo awon amofin loju
*Won tun ni kan fomo Audu je gomina apapandodo


Leyin iku Abubakar Audu, oludije fun ipo gomina labe egbe oselu APC nipinle Kogi, eni to jade laye nikete ti ajo INEC kede wi pe eto idibo gomina to waye nipinle naa ku sibi kan, ni isele naa ti di ohun ti awon onwoye lagbo oselu ati eka imo ofin ti n forigbari nipa ona abayo si awon isoro to le tenten bi igba ti won fi lori omi.

Ninu eto idibo to waye lojo kokanlelogun osu kokanla odun yii (21/11/15) ni Audu to je oludije labe egbe oselu APC ti n lewaju pelu iye ibo 240,867. Nigba ti akegbe re lati inu egbe oselu PDP, eni to tun je gomina ipinle naa, Idris Wada, ni iye ibo 199,514 ko to wa di wi pe ajo INEC kede wi pe eto idibo naa ku sibi kan latari kudiekudie to waye ni awon ibudo idibo ti apapo iye won je mokanlelaadorun (91).

Lara awon ibeere to n ja rainrain nile ni wi pe, se ogbeni James Faleke to je igbakeji oloogbe Abubakar Audu ninu eto idibo to waye naa ni yoo maa tesiwaju gege bi oludije ipo gomina lati pari awon agbegbe ti eto idibo naa yoo tun ti waye?

Gbogbo inu iwe ofin Naijiria ti odun 1999 ti a n samulo ni awon agba amofin yewo yebeyebe lai ri ogangan abala to soro ba iru isele to sele ni Ipinle Kogi. Won ni iru isele bee je ajoji, eleyii ti idahun san-ansan nipa re ko jeyo rara nibikibi ninu iwe ofin ile wa naa.

Ohun to si mu isele naa takoko ko ju wi pe, won ti dibo naa pari ni awon agbegbe kan, nigba ti eto idibo ko kesejari ni awon agbegbe mi-in eleyii to mu INEC so wi pe awon ibo naa ku sibi kan. To ba je wi pe won ti kede eni to jawe olubori ni, oro naa ki ba ma ti lojupo bi ese telo.

Ninu oro Amofin, Abdul Mahmud, amofin to mo tifuntedo ofin ile Naijiria, so wi pe abala to soro ba iru sele Kogi menuba gomina ti won ti yan sipo, ko so nipa eleyii ti won nibo re ko ti kesejari latari wi pe o ku sibi kan.


"Oro to wa nile yii takoko gidi gan-an. Iwe ofin odun 1999 ati agbekale ofin to ni i se pelu eto idibo ile yii ko yannana apeere iru isele to sele ni ipinle Kogi. Ajo INEC kede eto idibo naa gege bi ibo to ku sibi kan, nipa eleyii, Section 181(1) ti ofin ile Naijiria todun 1999 ko wulo," Ogbeni Mahmud se e lalaye bee.


Gegeg bi agbekale abala mokanlelogosan (Section 181) ofin ile Naijiria todun 1999 se se agbekale re, ori kinni so wi pe, ti gomina ti won ba dibo yan ba ku saaju ojo ibura gege bi iyansipo gomina, tabi ohunkohun to sele ti won ko fi ni le bura fun un, eni to je bi igbakeji re ni won yoo bura fun gege bi gomina. Eni naa ni yoo si pada yan igbakeji tuntun pelu ibuwolu idameji ninu meta ile igbimo asofin ipinle naa.


Labe agbekale ofin ti amofin Mahmud n soro o ba loke yii ni i se pelu oludije to ku saaju eto ibura iyansipo. Sugbon nipa ti isele to sele ni Ipinle Kogi, eto idibo ti bere, eto idibo naa si ku die ko pari ni oludije naa jade laye.

Sugbon ninu ero amofin Jiti Ogunye, ti o oun naa je okan lara awon amofin ti won mojuleja iwe ofin ile Naijiria, oun gba wi pe ko ye ki idaduro o wa rara, o ni oye ki ajo INEC tesiwaju ninu eto idibo naa ki won si kede eni to bori.

"Kii se Audu ati Wada nikan ni oludije ti n du ipo gomina. Awon egbe oselu ti won si n kopa ninu eto idibo naa koja APC ati PDP," Ogunye fi kun oro re bee.

Ju gbogbo re lo, minisita fun eto idajo, Abubakar Malami, ti so di mimo fun gbogbo elekajeka ti oro naa kan wi pe, pelu bi oro se ri yii, egbe APC ni lati fa elomii kale ti yoo ropo Audu Abubakar to doloogbe. Nigba ti iyoku ibo ni awon ibudo ibo ti won fe tun di yoo si maa tesiwaju.

Lara awon awuyewuye to tun jeyo ni bi awon egbe ti won polongo idibo fun oloogbe Audu Abubakar se n wi pe omo oloogbe, Mohammed Audu, ni ki egbe fa kale lati ropo baba re. Lara awon ti won kin oro yii leyin ni gomina ipinle Abia nigba kan ri, Orji Kalu.

Yato si eleyii, awon agbaagba egbe APC lati ekun ila-oorun ipinle Kogi naa ti kede atileyin won fun Muhammed, eni odun metalelogoji (43) to je akobi omo Audu Abubakar.

Sugbon ninu oro ti alaga fun egbe APC lapapo, oloye John Oyegun, fi da awon eniyan loju wi pe egbe APC ti ipinle Kogi yoo lo tun ibo abenu mi-in di lati mo asoju egbe naa ti yoo ma tesiwaju gege bi oludije.

Igbese ti egbe APC n sise le lori yii lo gbeyin yo nigba ti igbakeji Audu Abubakar, James Faleke, fi ibinu ko leta si alaga ajo INEC, Mahmood Yakubu. Faleke ni ohun ni gomina ti ilu dibo yan niwon gba ti Audu Abubakar ti silebora. O tun fi kun un wi pe, ajo INEC ko leto lati kede eto idibo naa gege bi eto idibo to ku sibi kan niwon igba to ti foju han wi pe egbe APC lo wole.

“Ti a ba ni ka foju inu wo daada, ko ye ki oludije tuntun wa jere ibo ti awon eniyan ti di sile, eleyii ti won ti ka si ara ilu leti saaju ki won tile to yan irufe oludije tuntun bee,” leta yii ni amofin Wole Olanipekun ko ni oruko ogbeni Faleke.

Falake ko sai tun fi kun un wi pe oun ni gomina ti ilu sese yan, ni o si dara ki ajo INEC tete se atunse ni kiakia.

Ninu oro ti akowe ipolongo fun egbe PDP,  Olisa Metuh fi sita, o ni nipa wi pe oludije labe egbe oselu APC padanu emi re ni akoko idibo naa fidi re mule wi pe egbe PDP ti jawe olubori. O si kesi ajo INEC lati kede Idris Wada gege bi olubori ati eni ti yoo je gomina tuntun.

"Ka maa se pasipaaro oludije laaarin meji eto idibo ki i se ohun ti a ri ka ninu iwe ofin ile Naijiria rara. Iku oludije APC fi da wa loju wi pe won ti padanu idije fun ipo gomina ipinle Kogi," Metuh fi kun oro re bee.

Ogbeni Metuh ko sai pe fun ikowefiposile minisita fun eto idajo, Abubakar Malami, pelu bo se si ajo INEC lona nipa wi pe ki egbe APC yan oludije tuntun.

Lori oro yii kan naa, Gomina Ayodele Fayose ti ipinle Ekiti ti naka aleebu si Aare Buhari gege bi enikan to n lo minisita fun eto idajo, Malami, lati dori oro kodo mo ajo INEC lowo. Oro yii ni Fayose so lati enu oludamoran re nipa oro-to-n-lo ati iroyin ayelujara, Ogbeni Lere Olayinka.

Ninu eto idibo abele eleyii ti egbe APC ti ipinle Kogi n mura lati se, awon onwoye lagbo oselu so wi pe oseese ko je Alhaji Yahaya Bello ni o jawe olubori. Alhaji Yahaya ni eni to gbe ipo keji ninu eto idibo abele to mu Audu je asoju egbe APC. Ninu eto idibo abele egbe APC naa, Audu ni iye ibo 1,109 nigba ti Yahaya ni iye ibo 703.

Wayio, ojo karun-un osu kejila odun yii (5/12/15) ni afojusun awon omo ipinle Kogi, eleyii to je ojo ti ajo INEC kede gege bi ojo ti eto idibo naa yoo maa tesiwaju ni awon ibudo idibo ti won fagile fun atundi ibo.



Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment