Ile ise Ologun seleri owo tabua fun eni to ba ri Boko
Haram
Ile ise Ologun ile Naijiria ti se afihan foto awon ogbologbo alakatakiti esin Islam,
Boko Haram bi ogorun (100) eleyii
ti won on wa lati mu. Awon wonyii
ni won se apejuwe won gege oloye agba ti
won on dari Boko Haram ninu ise ijamba
buruku ti won fi n da alaafia orileede Naijiria laamu.
Foto yii lo jade sita nigba ti won pe fun
ifowosowopo ara ilu lati tete ri won mu ni ibanu pelu ero Aare Muhammadu Buhari lati fi opin si aibale okan
ti Boko Haram da si orileede yii.
Oga agba awon omo ologun, Army Staff, Lt – Gen.
Tukur Buratai lo gbe awon aworan yii soke niwaju awon oniroyin l'Ojoru ose to
koja.
Akole awon ori foto naa ni i so wi pe ki awon ara
ilu se iranlowo nipa kikan si ile ise Ologun nigbakuugba ti won ba ri eyikeyi
awon eniyan to wa ninu foto naa nigboro aye.
Bakan naa ni won tun fi kun un wi pe ebun owo tabua wa fun enikeni ti
o ba le ran awon lowo lati ri awon
kannakori naa mu ni kiakia. Buratai ko sai fi okan awon ara ilu bale nipa abo won.
"Enikenike to ba kan si wa lati fun wa ni asiri ona ati ri awon won yii mu, a fi dayin loju wi pe a ko ni se afihan ohunkohun nipa yin fun enikeni eleyii to le se akoba tabi ijamba fun yin. Ipamo wa ni gbogbo ohun ti e ba ba wa so ati eni ti e je yoo wa lai han sode".
Awon nomba ibanisoro ti ile ise ologun fi sita naa ni yii: 0818155888,
08160030300 ati 07053333123.
Igbese tuntun awon omo Ologun ile yii ni awon onwoye kan ti n soro ba
bayii. Won ni bi ile ise ologun se n be ara ilu fun iranlowo fihan gbangba wi
pe agbara won ti fe pin tabi ko ti pin nipa igbiyanju won lati da segun Boko
Haram ti won ti di egungun eja si wa lorun. Nitori wi pe, gege bi ologun, o ye
ki won ni ogbon ete ti won samulo lati mu awon amokunseka naa bale.
Sugbon bi nnnkan se n lo yii dabi eni wi pe gbogbo ogbon ti won ni ni
won ti lo eleyii ti ko yi ohunkohun pada ni kiakia bi a se lero
Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, odun 2002 ni iko Boko Haram gbori soke ni
orileede Naijiria lati owo Mohammed Yusuf ko to wa di wi pe Abubakar Shekau n
ba lo gege bi adari. Awon kan gba wi pe
egbe naa nihun se pelu egbe alakataki kan ti a mo si al-Qaeda eleyii ti Osama
bin Laden da sile. Ni osu keta odun 2015 ni adari iko naa, Abubakar Shekau kede
jije olooto re si egbe alakatakiti kan
ni ile Iraq ti n je ISIL.
O kere tan, awon eniyan bi milionu meji abo ni Boko Haram ti so di
alainile lori nigba ti awon eniyan to le ni egberun lona ogun ti doku patapata
lati owo awon iko ti won fi oruko Allah se ise ibi.
0 comments:
Post a Comment