Bukola Saraki |
Won o je ki Saraki
o rona gba leyin to fun awon minisita Buhari lona lo
Ile ejo kotemilorun to kale siluu
Abuja ti da esun aare ile igbimo asofin agba, Bukola Saraki nu patapata. Ninu
esun ti Saraki gbe lo si ile ejo, ibe ni Saraki ti n ro ile ejo lati pase
jokoo-jee fun Code of Conduct Tribunal
(CCT) latari awuyewuye ti won gbe dide.
Bakan naa lo n wi pe ki ile ejo naa da gbogbo esun ti tiribuna gbe kaa laya nu
sinu omi okun agbadagbudu. Sugbon sa, kaka ki ile ejo se ohun ti saraki n pe
fun, iwe ofin ni ile ejo si ti won si kaa seti gbogbo mutumuwa. Won ni Code of
Conduct Bureau ni ase labe ofin lati gbe enikeni lo si ile ejo tiribuna nigba
to ba ye fun won lati se bee ninu ise won.
Saraki ni won fi esun metala kan eleyii to dale aisododo
nipa ijewo dukia eni ati awon iwa jegudujera ni awon akoko to je gomina ipinle
Kwara. Nibayii, ile ejo to gaju niluu Abuja ti pase
fun Code of Conduct
Tribunal (CCT) lati maa ba awon esun metala ti won
fi kan Bukola saraki lo lai si idiwo tabi idina kankan.
Iroyin tuntun yii lo jade lojo Eti to
koja yii leyin ti Saraki ati awon senato yoku fi ontelu lu awon minisita
Buhari, paapa julo, Rotimi Amaechi ti awon kan ti ni ko ni yege.
Ti e ko ba gbagbe, ojo karun-un ati
ojo kefa osu kokanla odun ta a wa yii ni ile ejo tiribuna yoo tun maa pada
jokoo lati ye Saraki wo bi igba ti tisa ba n gbon ise akekoo wo yebeyebe.
Lori esun jegudujera kan naa, ile ise ti n
risi iwa idaran niluu London, National Crime Agency [NCA] si n ba iwadii won lo
ni rebutu nipa minisita epo robi ile Naijiria nigba kan, Arabinrin Diezani Alison-Madueke
lori awon esun jegudujera ti won fi kan-an.
Bi o tile je wi pe awon agbofinro ilu London ti pada tu Madueke sile ko maa lo sile, sugbon gbogbo iwe irinna re pata ni won ti gba lowo re. Eleyii ti ko fun lanfaani lati tirafu jade niluu London titi ti gbogbo iwadii ti won se yoo fi kesejari.
Bi o tile je wi pe awon agbofinro ilu London ti pada tu Madueke sile ko maa lo sile, sugbon gbogbo iwe irinna re pata ni won ti gba lowo re. Eleyii ti ko fun lanfaani lati tirafu jade niluu London titi ti gbogbo iwadii ti won se yoo fi kesejari.
Nibi ti Madueke, obirin akoko ti o je aare
egbe awon orileede ti won ti n fo epo-robi lagbaye, Organization of the Petroleum
Exporting Countries (OPEC), ti n ronu kini o le je abajade iwadii awon olopaa
ilu London, Abba Moro o loju orun mo pelu bi Aare Buhari se siwe iranti kan-an.
Boya eyin gbagbe, losu keta odun 2014, awon
eniyan bi ogun, awon odo, ni won doloogbe nibi won ti n lakaka lati rise gba ni
eka ile ise ijoba apapo to n risi wiwole-wode, Nigerian Immigration Service.
Abba Moro lo je minisita feto abenu nigba naa,
to si je eni ti oro naa kan gbongbon, ni
awon ara ilu pe fun idaduro re lenu ise. Sugbon aare to wa nipo nigba naa,
Goodluck Jonathan, foju fo asise re da.
Asiri to tun tu nigba naa ni wi pe won fi eto igbanisise naa kowo je eleyii ti won ni kan dapada sugbon ti won ko lati se bee.
Awon Yoruba bo, won ni iyan ogun odun a maa jo ni lowo felifeli.
Asiri to tun tu nigba naa ni wi pe won fi eto igbanisise naa kowo je eleyii ti won ni kan dapada sugbon ti won ko lati se bee.
Awon Yoruba bo, won ni iyan ogun odun a maa jo ni lowo felifeli.
0 comments:
Post a Comment