"Ni Akute, awon ota ni won ba Amosun loruko je" Ijoba
ipinle Ogun
Ile ise ijoba ipinle Ogun ti pe
akiyesi awon ara ilu si iroyin eleje kan ti iwe iroyin kan gbe jade wi pe
wahala wa laaarin awon oloja ti won gbe ni agbegbe Akute ati gomina ipinle
Ogun, Senato Ibikunle Amosun. Iwe Iroyin to jade naa tun fi kun un wi pe atunse
awon oju ona lati Akute titi to fi de Alagbole to wa ni ijoba ibile Ifo ti n lo
lowo lo je ise owo awon egbe oloja eleyii ti won ni ijoba Amosun ko lati ba won
dasi.
Gege bi atejade ti akowe agba fun ile
ise ijoba ti n risi ise ode ati igbayegbadun ara ilu, Engr. Kayode Ademolake fi
sita lojo Aje to koja yii se so. O salaye wi pe ohun to foju han gbangban ni wi
pe ijoba ipinle Ogun ti gbe ise oju ona Sango-Ijoko-Agbole-Akute-Ojodu Abiodun,
eleyii to wa lara oju ona ti won soro ba, fun awon agbase se.
Ogbeni Kayode lo je ohun ijoloju lati
gbo wi pe awon kan an pa iru iro bantabatan bee wi pe kii se ijoba lo n se awon
ise oju ona naa. "Ko ni dara ki a maa da idagbasoke ilu po mo oselu sise,
idagbasoke ye ko je ojuse gbogbo wa ni". Ogbeni Kayode tun soro
siwaju sii...
"Bi o tile je wi pe awon ise naa
fa seyin lenu ojo meta yii latari awon ojo suuru ti n ro, sibesibe eyi ko fi
ibi kankan mu adiku de ba ileri ati ife gomina si awon ara ilu. Ohun to tun
daju ni wi pe ijoba to wa lode yii ko ni loju orun ayafi ti o ba mu awon ileri
re pata se. Pataki ibe ti mo tun gbodo fi kun ni wi pe aimoye ise lo wa lowo wa
ti a n ba lo lati ri wi pe awon oju ona wa se e gba fun awon eniyan wa pelu
irorun. Lara awon oju ona ti ise ti n tesiwaju ni oju ona Sango-Ijoko, Ope-Ilu,
Agbado, Abule Ekun, Akute- Alagbole, Owode-Ijako eleyii towa laaarin oju ona
Eko si Abeokuta, Sagamu-Ogijo, Ijebu Ode ati bee bee lo.
0 comments:
Post a Comment