Ti a ba ranti ibi
taa ti n bo, ti a ba si sakiyesi ibi taa de ninu igbe aye wa, idi ope wa yoo
foju han gban-angba. Lopo igba ni a ki i
se iranti awon eniyan ti a jo n bo, meloo ninu won lo ni oore ofe lati wa ni
ipo taa de tabi wa laye lonii. Kootu wo ni awon to ti ku fe pe Olorun oba si? E
fun mi lanfaani lati so nipa awon ore mi meji kan ti mi o le gbagbe laelae.
Ile eko alakobere
Metodiisi to wa ni Ekotedo ni mo lo niluu Ibadan. Mo feran Musa gidi gan-an
nitori wi pe o je olopolo pipe eda eniyan. Eyi si maa n je ki n wo gege bi
enikan ti ki i se eniyan eleran ara lasan. Musa le ma wa si ileewe fun odindi
ose meta, igbakuugba to ba wuu ko yoju, kosi ibi to wu ka ti de lori ise kan ti
a ti n baabo, kosi bi ise ohun sele le to loju wa, Musa o tun tayo ju gbogbo wa
lo ni koda ko je asiko idanwo nikan lo yoju.
Orisii opolo Musa
a maa ba mi leru nitori mi o fi ibi kankan sun mo o nibi ise opolo, sibe
joojumo lemi n wa sile iwe. A si maa wu mi ki n dabi Musa ore mi atata olopolo
pipe bi alajo Somolu.
Okan lara awon
ore mi kan naa tun wa to tun fara pe e, Hamzat. Ki i se opolo pipe lo mu Hamzat
wu mi. Sugbon mo feran Hamzat nipa ewa ara to ni. Ti won ba ni okunrin rewa, lati
ojo ti won ti bi mi saye mi o ti ri iru ewa Hamzat ri. Hamzat mo fefe, pupa re
si la kedere bi igba ti imole yo loju orun ni kutukutu owuro. Oju re gunrege,
eji enu re a si han foforo laaarin ehin funfun nigba o ba rerin muse sini.
Irun ori re a maa
gbon leuleu bi o ba n rin lo birun eebo. (Omo Niger Republic loke oya ni iya
re, won si ni iya re lo fi irun naa jo). Olorun tun jogun oro enu tutu fun
Hamzat, to je wi pe to ba n binu soro eniyan ki i mo nitori ohun tutu enu re ki
i lo soke rara.
Sugbon lonii,
opolo Musa o wulo mo, ewa ara Hamzat ti baje. Ibanuje lo maa n je fun mi nigba
ti mo ba se iranti awon ti won ti fi igba kan damilorun ri.
Imo je ohun to se koko si igbasi aye eda. Ebun nini si tun je oore-ofe lati odo Olorun lati se aponle eda fun igbega. Sugbon olubori ibe ni iwa. Awon kan pe ni isesi tabi iha. Ohun kan naa ni gbogbo re jasi.Isesi eni lo maa n fi iwa owo eni han. Iwa owo eni si ni opakutele si iha eni si ohunkohun ti a ba gbe dani tabi doju ko laye.
Bi Musa se ni
opolopo opolo to fun iwe kika, iha to ko si eko re pada so imo re di akurete. Nipa
wi pe o maa n sa ni ileewe ni gbogbo igba.
Igba meji otooto
ni mo tun yara ikawe meji otooto ka nigba naa. Musa ko tun yara kan ka leemeji
ri.
Emi pada wo ile
iwe girama, Musa o le lo. Won tun gbami wole si ileewe giga, Musa gbiyanju
sugbon aso o ba Omoye mo.
O ku die ka jade
ile iwe alakobere ni Hamzat bere si ni tele awon orekore ti won n jijo lo maa
mu imukumu. Igba ti mo wo ile iwe girama, Hamzat na a o le wole pelu wa nitori
wi pe igbo mimu ti yi lori. O si ti bere si ni wi kantakantan kiri. Okan mi
baje. Awon obi re mu lo seyin odi lati lo toju re. Igba ti Hamzat yoo fi pada
wa sile. Awo ara re ti si, oju re ti hunjo bi oju arugbo, omo pupa ti jona bi
eyin ape akara, irun ori re ti reje tan bi eni lapalapa n baaja laaarin ori. Bakan naa ni gan-angangan ko kuro lara re tan
patapata.
Igba miiran yoo tutu bi omi inu amu. Bee ba n
baa soro ko ni wi ohunkohun. Igba mi si re e, erin odi ni o maa rin lenu.
Hamzat o da mi mo
mo lojo ti mo duro ki i, ti Musa ba ri mi a foju pamo. Iwa owo Musa o je o kawe
bee ni ko rise kankan ko yanju. Okunrin olopolo pipe igbaani wa deni ti n
taraka lese-titi
Ipokipo
ti a ba de laye, e je ka dupe fun Olorun oba. Awon kan dara ju wa lo, sibesibe
won ko ni ru anfaani ti a ni. Opolopo lo ti ku, aimoye lajo bere odun yii sugbon
ti won ko di akoko yii. Kii se wi pe awa lape ju lo, oore ofe lari gba.
Olayemi
ni oruko mi, ilu ti mo feranju laye ni Naijiria, ilu awon eniyan rere, ilu
olokiki nla ati awon olododo eniyan, ki Oluwa bukun ilu naa. Amin
0 comments:
Post a Comment