*Ajimobi
fogbon juko oro si Ladoja
Ninu alaye to te Olayemi Oniroyin lowo, Abiola Ajimobi to je
gomina ipinle Oyo ni idarapo Alao-Akala mo egbe APC dabi igba ti alagbara meji
ba gbimopo lati di okan soso. O ni igbese tuntun yii yoo so awon di erikina nla
ti enikeni ko ni le da lona.
Leyin awuyewuye ati awon
oro ti n lo nigboro nipa wi pe gomina tele fun ipinle Oyo, Christopher
Alao-Akala n mura lati darapo mo egbe APC ti pada jade lenu Akala funra re
bayii. Oro yii ni Alao-Akala, eni ti awon kan tun un pe ni Omo Iya Alaro, fi da
awon eniyan loju nikete ti ile ejo kotemilorun pada da Ajimobi lare gege bi
gomina ti o maa tesiwaju ninu isejoba ipinle
Oyo. Akala ni gbogbo eto lo ti to, oun si ti setan lati darapo mo egbe APC ti
won dasile lojo kefa osu keji odun 2013.
"Gomina ipinle Oyo
tele je eekan nla ti ko se fowo ro seyin lagbo oselu ipinle Oyo ati ni Naijiria
lapapo. Eerin nla niluu Naijiria, to ba de ilu London, eerin naa ni yoo tun maa
je. Bakan naa, eerin nla ninu egbe PDP ati Labour, eerin naa ni yoo tun maa je
to ba de inu egbe APC.
"Ni ojo toni, ti a ba
ni ka maa so nipa awon to lenu nibe ninu oselu ipinle Oyo, a maa so nipa
Ajimobi, Akala ati Ladoja. Ibasepo emi ati Akala yoo mu wa di alagbara eleyii
ti enikeni ko ni le ko lona. Nigba ti akogun meji ba dokan, talo tun seku? A ko ni i lo lati daruko enikeni, awa nigi
nla ti ko se e kolu." – Ajimobi se lalaye bee.
0 comments:
Post a Comment