Smiley face

Lati je eniyan alagbara lodun 2016

#Ogulutu #11

Nigba ti a wa ni kekere, ti awon obi wa ba sakiye wi pe a n ko awon ore ti ko dara. Iru gbolohun yii maa n jade lenu won: "fi ore re han mi, ki n le so iru eni to je." Awon obi wa gba wi pe iru ore ti a ni tabi awon eniyan ti a n ba rin maa nipa ninu igbe aye wa. Sugbon maa se atunto si gbolohun naa, maa si so bayii wi pe: “fi ore re han mi, KI N LE SO IRU ENI TO O JE". 


Bi a se n mura lati je alagbara ninu odun 2016, eni ti yoo se aseyori ninu awon idawole re gbogbo, awon ore kan wa ninu aye wa to ye ka yago fun. Bakan naa si ni awon ore kan wa to ye ka sunmo ki irin-ajo wa ninu odun tuntun le gunle si ebute ogo.

Ninu ero mi, ati oye mi nipa oselu Naijiria, mi o ro wi pe Aare ana, Goodluck Jonathan, baadi gege bi olori tabi eda eniyan kan pato. Ohun to mu akurete ba isejoba re eleyii to si so di alailagbara ninu eto idibo gbogboogbo todun 2015 ko ju orisii awon eniyan to mu mora lo ninu eto isejoba re. Orisii awon ore to sun mo wa le mu wa wu iwa ologbon eleyii to le je ka jo bi alagbara lori ohun ti a dawo le, bakan naa si ni idakeji re.

Eniyan le di olosi nipase orisii awon ore ti n ba rin. Bakan naa ni eniyan le di oloriire nipase eni to sun mo ni ju lo. Iru awon eniyan wo le n ba rin? Kini awon ohun te jo maa n so nigba gbogbo ti e ba pade? Kini erogba ati afojun awon ore yin fun igbe aye?

Ti awon idahun yii ko ba ti ba igbe aye tuntun to wu yin gbe mu tabi erogba ati ipinnu yin fun odun tuntun, mo be yin nitori Olorun to da orun ati aye, e yago fun won.
Ko si ogbon ti e le da, kosi ona ti e fe gbe gba, awon wonyii yoo nipa ninu irin-ajo yin ayafi te e ba yago fun won patapata. O le nira, sugbon ibere oriire yin ni.

Bi e se n gbiyanju lati ja awon ore kan sile, e tun maa foju sile lati yan awon ore tuntun to niise pelu igbe aye to wu yin gbe tabi ohun te e fe gbese. Boya orisii okoowo kan lo wu yin se, ogbon ati imo kan lo wu  yin ko, o si le je wi pe aye iwa mimo to dara ju eyi te n gbe tele lo wu yin lati gbe, e sunmo awon eniyan to le ran yin lowo.

E niba mule tigbo, dandan ni ko gbohun eyekeye. Eni mule ti kootu, ko ni salai gbohun akowe. Bi eniyan ba sunmo ojo eniyan, eniyan ti ko lafojusun fun igbe aye, eniyan ti ko laponle tabi orisii eda eniyan ti ko mo ohun ti i n se, kosi bi iru awon nnkan bayii ko se ni yi ni lara ti eniyan ba yan iru won lore.

Lopo igba mii, lati je alagbara eniyan, eniyan ni lati darin lai ni ore kankan. O dun 2016 ko nipe de, e se ohun gbogbo lati wa ni igbaradi ke e si ri wi pe e wo inu odun naa lo gege bi alagbara to ti pinnu lati di alaseyori ninu gbogbo idawole re gbogbo.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment