*Kilode ti Tinubu ko da soro naa?
Lojo Aje to koja yii ni rugudu ti n lo lagbo oselu nipinle Kogi tun bureke si i nigba ti Ogbeni James Abiodun Faleke mu iwe ipejo re lo siwaju ile ejo ti n gbo awuyewuye to suyo leyin idibo ti a mo si tiribuna nipinle naa.
Aimoye awon eniyan ti won je alatileyin, ore ati ololufe Faleke ni won tele lo si ile ejo naa lati fi iwe ipejo naa sile fun akowe kootu.
Lara awon eniyan ti won tele Faleke ni Mohammed Audu to je omo oloogbe Abubakar Audu ati agbejoro Faleke to siwaju gege bi Balogun.
Esun pataki ti Faleke te siwaju ile ejo naa ni wi pe, ona aito lo je gege bi ajo INEC se kede eto idibo ojo kokanlelogun osu kokanla odun yii (21/11/15) gege bi eto idibo to ku sibi kan leyin ti egbe to bori ti foju han gbangba.
Bakan naa, Faleke fi kun oro re wi pe, oun lo ye fun ajo INEC lati kede gege bi gomina tiluu dibo yan ki i se Yahaya Bello.
Nibayii, awon agba egbe APC lati ekun Iwo-oorun ipinle Kogi ti n mura lati se ipade po pelu Faleke nibi ti won yoo ti ma petu si i ninu lati faramo ipinnu egbe lori oro to wa nile naa.
"Gbogbo ohun to ba ye ka se pata ni a gbodo muse lati ri wi pe oro to wa nile yii ko baje koja atunse. A fi n da awon ololufe egbe wa loju wi pe a o bu omi tutu si oro naa. To fi je wi pe Faleke yoo lo fa iwe ipejo naa ya, titi gbogbo re yoo si yanju patapata. Ipinnu egbe se pataki, sebi ti omode ba n gegi nigbo, agba ni i mobi ti o wosi. Agba ki i si wa loja, ki ori omo tuntun o wo," Oloye Richard Asaje lo se lalaye bee.
Wayio, amofin to tun je ajafeto omoniyan, Ogbeni Emmanuel Owotunse ni awon igbese ti Faleke n gbe dabi igba ti eniyan ba n towo bo inu eeru gbigbona, kosi igba ti ko ni fika jona.
"Bi Faleke se gba ile ejo lo dabi igba to n te egbe loju mole, eleyii ti abamo le kangun oro re ti ko ba se suuru. Egbe mo ohun ti won se, ti Faleke ko ba si fi owo re sibi to ye, afaimo ko ma towo bo eeru gbigbona ti yoo jo nika. Eniyan ti ko kopa ninu eto idibo abele egbe ko le di gomina. Eewo ni. Faleke ko kopa ninu eto idibo abele egbe APC, ti won ba fa kale, owo kan ni egbe PDP yoo gba danu ni kootu leyin to ba di gomina," Ogbeni Owotunse se lalaye bee.
Ninu oro Owotunse eleyii to se ni Lokoja to je olu ilu Kogi lo tun fi kun wi pe, oun ti n ki Faleke laya ko ju nipa ajosepo re pelu Bola Tinubu lo.
"Awon agbejoro ti won gba Faleke lamoran ni won yoo pada se akoba fun un. Igbakeji gomina nipo Faleke lati ibere pepe, kilode ti ojukokoro ipo gomina wa n feju mo o losan gangan? Bo tile ni ajosepo to danmoran pelu Tinubu, o gbodo gba kadara ko ma ba gba kodoro," Owotunse fi kun oro re bee.
Bakan naa, Mohammed Audu to je omo oloogbe Abubakar Audu kede atileyin re fun Falake gege bi ife okan awon agba idile baba re. Eleyii ti aba naa jade leyin ipade molebi to waye ninu idile oloogbe naa.
" Mi o ro wi pe awon agba idile wa nikan ni won fe lati ri Faleke gege bi eni to ye nipo gomina, inu baba mi ti n be lorun gan-an ko le dun pelu bi awon kan se gbimopo lati yan igbakeji re je. E je ka maa se ohun gbogbo pelu iberu Olorun oba Allah. O ni lasan la ri, kosi eni to mo ile ti o mola," Mohammed fi kun oro re bee.
Pelu bi nnkan se n lo yii, awon onwoye nipa oro oselu gba wi pe ina Faleke ti n jo lori omi, onilu re mbe nisale odo ni. Won ni okan ninu awon omo ti Tinubu to dagba ninu oselu ni Faleke je, to fi je wi pe kosi ohun ti Tinubu ni ko se ti ko ni se. Bi nnkan se wa ri yii, ti a ko gbo ohunkohun ni gbangba nipa Tinubu lori oro naa, o ni lati je wi pe nikoro ni Tinubu ti n ba Faleke soro. Eleyii ti oro naa si je awon oro iwuri ti n mu Faleke maa saya gbangban to si ko lati gba si egbe lenu.
Pada sori oro ti amofin Owotunse so, se kadara ni o pada keyin oro Faleke ni abi kodoro?
0 comments:
Post a Comment