Gomina ipinle
Ekiti, Ayodele Fayose, sodun keresimesi fun awon egbe mekaniiki atokose tipinle
Ekiti, Nigerian Automobile
Technicians Association. Nibi ipade ti Fayose se pelu won,
eleyii to waye lojo Isegun to koja yii ni olu ile-ise egbe naa to wa ni
Adebayo, Ado-Ekiti ni gomina ti n dupe atileyin ti egbe naa se fun un.
Ninu oro re,
Fayose ni dandan ni ki oun wa fi emi imoore han. Nitori eni ta a se loore ti ko
dupe, bi igba ti olosa koni leru lo ni.
“Ipo ti mo de
lonii yii, mo debe nitori wi pe e duro leyin mi ni. O si ye ki n maa fi emi imoore
han nigba gbogbo nitori wi pe e ko pada leyin mi. Mo wa ki yin ni lonii, mo si
wa bayin yo ayo odun,” Fayose se lalaye bee ninu oro re.
Bakan naa ni
Fayose tun fi kun un ninu oro re wi pe, oun ko ni pada ninu awon ileri ti oun
se saaju eto idibo lati ri daju wi pe anfaani ijoba awaarawa kari gbogbo eniyan
ipinle Ekiti pata.
Leyin eyi ni
gomina Fayose fi ebun keresimesi ta awon egbe atokose naa lore. O ni oun n se
eyi lati ba won yo ayo odun keresimesi ati odun tuntun ti n bo lona. O si
sadura wi pe odun ayo nigbogbo omo egbe naa yoo se.
0 comments:
Post a Comment