Smiley face

Igbese, akoko ati agbara fun odun 2016

#ogulutu #12

Ti eniyan ba fi opolo sinu ikoko-isebe kan ti omi kun inu re, ki eniyan wa gbe ikoko naa ka ori ina. Bi ina se n jo, ti omi naa n gbona sii ni opolo naa yoo ma se amulo agbara iseda inu ti Olorun fun lati farada omi gbigbona naa. Iwadii awon onimo ijinle fi ye wa wi pe, opolo ni agbara inu lati  farada omi gbigbona de awon akoko kan to lapere.


Bi omi yii se n gbona sii ni opolo yii yoo ma mu agbara inu re jade lati farada gbigbona omi naa. Sugbon nigba to ba de awon akoko kan, opolo naa ko ni le fi ara da omi gbigbona naa mo, yoo si wu bi ko fo jade.

Sugbon ni akoko yii, koni si agbara fun un lati fo jade mo; yoo o ti re. Agbara to ye ko fi fo jade lo ti n lo lati fi farada omi gbigbona ti n jo o lara. Laipe, omi gbigbona naa yoo si seku pa a.

Ibeere to jeyo jade ni wi pe, kilo pa opolo yii?

Mo fe ki e ronu sii. Eyin le gba wi pe omi gbigbona lo seku pa opolo yii, sugbon ko ri bee. Opolo naa ku nitori wi pe ko mo akoko to ye lati fo jade ninu omi gbigbona naa ni.

A ti n wo inu odun tuntun lo, e ma se asise nipa mimo akoko to ye ke e gbe igbese pataki ninu irin ajo yin. E ma duro de igba ti agbara yin yoo tan ki e to pinnu lati fo jade. Ogbon okoowo kan le ni lokan, e ri daju wi pe e gbe igbese ni kiakia. 


To ba wu yin lati pada si ileewe tabi ko ise kan, e se kiakia. Ti a ba peju lori imi, esin keesin ni o ba yin  lori re. Awon atunse kan lo ye ke e se ninu idile yin, lori ise ti e n se tabi pelu Eleda yin, e ri daju wi pe e se ni kiakia. Ijamba nla wa ninu fifi akoko sofo tabi ki eniyan kuna lati gbe igbese to ye ni akoko to ye. 

Aa ma pade ninu odun tuntun pelu oore ofe Olorun. Mo dupe fun atileyin yin ninu odun 2015.  

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment