Smiley face

“E sora fohun to le fa ijamba ina”- Oga panapana ilu Eko

*O tun ni awon irinse awon ti darugbo

 Oga agba ileese panapana ti ijoba apapo, Federal Fire Service, eka ti ipinle Eko, Ogbeni Aderemi Olusola Theophilus ti ro awon eniyan lati sora ni asiko poposinsin odun taa wa yii. Ninu oro re, eleyii to so lori telisan ipinle Eko, o ni ona to ya ju lati yago fun ijamba ina ni ki awon eniyan sora fun awon eroja to le tete gbanaje. Bakan naa lo tun gba awon odo niyanju lati sora nipa fifi isana sere ni akoko yii, nitori akoko oye yii ma n se iranlowo fun ina lati tete gbera so.


Ogbeni Aderemi tun so siwaju wi pe, ona lati dena ijamba ina ko yo awon obirin ile sile nipa akiyesi to peye nigba ti won ba dana. Bakan naa lo tun fi kun wi pe, ki awon eniyan maa ri daju wi pe gbogbo eelo ile ti n lo monamona ni won pa nigba ti won ba fe jade. Ko sai gba awon awoko oju popona lamoran lati yago fun iwa gbigbe epo sinu keegi ninu oko. O ni awon kan wonyii le sokunfa ijamba ina ojiji.

Bakan naa, ogbeni Aderemi ko sai menu  ba ipo ti awon irinse ile ise panapana ijoba apapo tilu Eko wa.

"Ohun to daju ni wi pe, ise wa ko le rorun lai ni awon irinse igbalode to je ojulowo. Pupo ninu awon irinse wa ti a n lo ni won ti dogbo; gbogbo igba ni won baje nitori igba ti lo lori won. Ko ba dara ti ijoba apapo ba le se iranwo nipase rira awon irinse ati oko tuntun eleyii ti yoo ran wa lowo lati daabo bo dukia ati emi awon ara ilu lapapo," Ogbeni Aderemi fi kun oro re bee.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment