Awon Yooba bo, won ni odoodun la a rorogbo; odoodun laarawusa; sebi odun ko ni de ka ma romo obi lori ate.
Aimoye ero pitimu ni won ya wo ile ijoba Ipinle Eko
lojo Isegun to koja yii nibi ti ayeye olodoodun orin keresimesi ti ma n
waye.
Awon komisanna, awon osise ijoba ipinle Eko, awon
asaaju ninu esin igbagbo ati awon ara ilu ni won jijo gbe ohun soke
korin lati fi yin Oluwa fun iwasaye Jesu olugbala araye.
Ninu oro gomina Ipinle Eko, ogbeni Akinwumi Ambode wi
pe akoko keresi kii se fun yalayolo odun nikan, bikose akoko fun ope fun
Olorun ati sise afihan ife si omo lakeji wa. Ambode tun lo akoko naa
lati ki gbogbo olugbe ipinle Eko ku odun keresimesi ati odun tuntun ti n
bo lona.
0 comments:
Post a Comment