Smiley face

Igbaradi fun odun 2016


Bi odun se n pari lo, dandan ni fun wa lati wa ni igbaradi fun odun tuntun. O se pataki, ki a ma ba a bo sinu awon asise kan naa ti a kosi ninu odun 2015 to n kogba sile diedie yii. Yato si eyi, a ni lati lakaka fun itesiwaju lori awon ona ti a ti yege ki igbeye to larinrin le je ti wa.


Igbaradi fun odun 2016 ni lati wa ni ibamu pelu iru eni ta a je, iru igbe aye taa n gbe , igbese to wu wa lati gbe ati awon ipinnu wa fun odun tuntun .

A ni lati ni ipinnu gege bi omo ileewe, osise ijoba, onise-owo, olokoowo, baale ile, iyawo ile, oloselu, asaaju esin, obi, omo, onibara, oloja, abbl.


Awon ayipada rere wo la fe ko de ba wa ni ipo ti a ba ara wa? Kini awon atunse ti o ye ka mu ba igbe aye wa? Kini isoro ti a ni, ona wo ni a si fe gba yanju re? Kini ero wa ati ipinnu wa fun odun tuntun? Kini awon ohun ti a fe, ona wo la fe gba lati ri awon nnkan bee? Kini awon ohun to duro niwaju wa gege bi ipenija, ogbon wo la fe da lati koju ipenija naa pelu isegun?

Awon nnkan yii la ni lati ko sile sinu takada funfun. Idi pataki ti a fi gbodo ko won sile ni wi pe, ni awon aye kan, ninu irin-ajo wa ninu odun tuntun, a ma niilo lati se agbeyewo awon ohun ti a ko sile wonyii. E yi yoo ran wa lowo lati mo nipa ibi ti a ti se aseyori ati awon ibi ti ise ku si lati se ki erogba wa fun odun tuntun le kesejari.

Lara ohun to tun wu mi ki n menuba ni isoro isuna owo, eleyii to wopo ninu igbe aye eda.  Lati bo ninu isoro isuna owo, ohun kan ti a gbodo kiyesi ju lo ni bi a se n na owo ti n wole fun wa.

Opolopo ni won lero wi pe isoro ti awon ni ni wi pe, owo ti n wole sapo awon kere, sugbon pupo awon eniyan ti won ro bayii lo je wi pe isoro won gan-an ni ona ti won gba na owo won.

Gege bi iwadii to daju nipa eto oro aje ati isuna owo kan se gbe kale, iyato kan gboogi eleyii to mu olowo maa lowo sii ti talaka si n dolosi sii ni bi won se n na owo won kii se bi owo se n wole fun won. Pupo awon mekunnu lo je wi pe pupo owo won ni won maa na lori bukata anadanu.

Kini apeere orisii bukata-anadanu?

Bukata-anadanu ni awon ohun ti gbon ni lowo lo. Bukata-anadanu ni awon ohun ti a n nawo le lori ti ko wulo si igbesi aye eni. Bukata-anadanu ni awon ohun ti ko mowo wole sugbon ti n mowo jade lapo eni. Awon kan wonyii lani lati sora fun gidigidi bi a se n mura lati wonu odun tuntun lo.

Gbogbo igba ti foonu tuntun ba ti jade ni elomii n kowo le e lori. Awon kan tile feran aso ebi ni rira nigba gbogbo. Kii se gbogbo aso ebi ni eniyan n ra, kii si se gbogbo ode ti won ba pe eniyan si leeyan an lo. Kosi bi owo ti n wole fun wa se kere to, ti a ba fi eto ati opolo ori pipe nawo, igbe aye wa yoo dun.

Awon olowo won kii nawo bi mekunnu. Awon ohun ti o mowo wole, ti o pawo woles ni olowo n nawo le lori. Idi ni yii ti won fi n lowo sii lojoojumo. Ti eniyan ba ni okowo kan, ko si ohun to buru taa ba ronu ati so okoowo naa di meji. Olokoowo meji n ronu bawo ni o se le di meta, bi eniyan se n dolowo naa nu-un.

Bi a ti n se ipinnu fun odun tuntun, e je ka kiyesi awon ona ti a na owo wa si pelu. Ti a ko ba se bee, oro wa le dabi eni ti n fi ajadi apere ponmi lodo. Odun 2015 ko ni di wa meru lo o. Amin.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

4 comments:

  1. I can live my day without coming here to rayed about you. You are so talented and blessed beyond human understanding. Just keep it up. One day, the world will hear about you. Thank you so much for the message. Am Olayemi from NYC

    ReplyDelete
  2. @ Olayemi Mopelola thank you so much. God bless you

    ReplyDelete