Reverend Chukwuemeka Ezeugo |
Ile ejo to gaju
nile yii ti kede ojo kerindinlogbon osu keji odun ti n bo (26/02/15) gege bi
ojo ti igbejo adari ijo Christian Praying Assembly, Reverend Chukwuemeka Ezeugo, ti gbogbo eniyan
mo si Reverend King yoo ma waye.
Reverend King yii
lo pe ejo ko-temi-lorun latari ejo iku ti ile ejo giga ti ipinle Eko da fun-un.
Ile ejo to gaju
yii, nibi ti Onidaju Walter Onoghen ti n joko ni o ti sun igbejo naa siwaju
nigba ti awon agbejoro fun igun mejeeji bere si ni gba oro naa bi eni gba igba
oti, ti won si tun bere iyan jija niwaju adajo.
Olori eka idajo
ati komisanna fun eto idajo ipinle Eko,
Onidajo Adeniji Kazeem, eni to farahan ni ile ejo naa pelu Arabirin Idowu
Alakija ro ile ejo naa lati da ipejo tuntun naa nu, ki won si tele idajo ile
ejo giga ipinle eko eleyii to ni ki won yegi fun maanu naa.
Reverend King,
eni to koko farahan nile ejo lojo kerindinlogbon osu kesan-an odun 2006 lori
esun mefa to dale ipaniyan ati igbiyanju lati paniyan.
Ninu awijare re,
okunrin naa ni oun ko jebi awon esun naa. Sibesibe, onidajo Joseph Oyewole ti n
joko nile ejo giga ilu Eko to wa ni Ikeja da ejo iku fun un lojo kokanla osu
kini odun 2007 lori esun ipaniyan okan ninu awon omo ijo re, Ann Uzoh.
Ninu esun ti
ijoba ipinle Eko fi kan Reverend King lo n wi pe, okunrin naa da epo bentiro si
ara awon eniyan marun-un kan. Lara awon eniyan naa si ni Uzoh to doloogbe lojo
keji osu kejo odun 2006 wa latari isele to sele sii lati owo Reverend King .
0 comments:
Post a Comment