Gege bi oro awon
Yooba,"eni Sango ba toju re wole, eni naa ko ni ba won bu oba Koso
laelae." Okunrin kan to pe ara re ni Cde Zenzele Nkosi lori FACEBOOK lo
salaye ijamba moto to sele si i nipa iwa oti mimu pelu oko wiwa. Okunrin naa se
afihan foto oju-apa to gbe jade nibi isele naa eleyii to ti n jina. Bakan naa
lo si n gba awon eniyan niyanju lati yago fun oti mimu pelu moto wiwa.
Ninu alaye Nkosi,
okunrin naa salaye wi pe awon ore oun meji ti won wa pelu oun ninu oko naa lo
ku, oun nikan ni ori koyo. Awon meji yoku ti padanu emi won danu latari
wiwako-muti.
"Oko naa baje koja atunse, awon ore mi meji ti won wa ninu oko naa si ku loju-ese. Mo je oloriire lati wa laye. Too ba wako, ma muti; too ba muti, ma wako. Mimu oti wako je pakute iku ti n duro deni. Ti o ba fe wo oko ni akoko poposinsin odun taa wayii, ri daju wi pe direba re ko mu oti, o gbodo tun je eni ti ara re bale daada. Gba mi gbo, ile aye yii ko too pon," Nkosi fidi alaye re gunle bee.
Atejade Nkosi
eleyii to se lojo keje osu kejila odun yii (7/12/15), ni nnka bi aago meta osan
ku iseju mejila ni awon eniyan bi ogorun mefa (600) ti se atunpi atejade naa. Nigba
ti awon eniyan bi ogofa (120) baa kedun labe iriwisi re titi di bi ago mokanla
ojo Eti to koja yii ti OLAYEMI ONIROYIN se abewo si ikanni re lori ayelujara.
Die lara ikini
ati ibanikedun ti awon eniyan se fun arakunrin naa ni yii:
M'lori Mlori Hardy: Cde...ki Oluwa
fi orun ke awon to ti lo. Inu mi dun si bo se lo irora re lati fi se kilokilo
ati ijigiri fun awon eniyan. Akoni loo se.
Sibiya Magoodies: Gbogbo ohun ti
yoo sele seda laye lo ti wa ninu akosile Oosa Oke. Sugbon maa fi ope fun Oluwa
wi pe o wa laaye lonii. Ki Oluwa bu tutu si okan awon eniyan ti won padanu awon
eniyan won.
0 comments:
Post a Comment