Smiley face

Omo Wasiu Ayinde di agbejoro tuntun

 Ese ko gbero ni Imperial Hall to wa ni Lekki Phase 1 ni ilu Eko lojo kerinlelogun osu kejila odun (24/12/15) nibi ti Oba Fuji, Wasiu Ayinde Marshal, ti gbe n yo ayo idunnu fun omo re, Basirat Damilola Anifowose to di agbejoro tuntun. 


Ojo kerindinlogun osu kejila odun (16/12/15) ni won gbe iwe eri le Damilola lowo, ti awon agba looya si faa wo agbo won nibi ipade igbaniwole to waye niluu Abuja.

Ori ire nla ati ayo idunnu lo je fun gbogbo ebi, ore ati ojulumo K1 nigba ti awon eniyan n ba a dupe lowo Olorun fun ore idunnu to darapo mo ebi re nibi ayeye weje-wemu to waye ni aisun odun keresimesi to koja yii.

“Gbogbo ohun ti Olorun ba se fun eda laye, ope lo ye ko du. Nitori kii se mimoose eda, Olorun ni lo n fun eda se. Inu mi dun lonii, mo ti di baba looya, Alhamdulilah,” K1 se lalaye bee.

Aimoye awon gbajumo lagbo amuludun ni won pejupese sibi ayeye naa lati ba K1 yo ayo omo re to de. Lara awon ni Olamide (Mr. Baddoo), Dayo Amusa ati Fathia Balogun.  Awon ilumooka ti won tun wa sibi ayeye naa ni Kemi Afolabi ati Kehinde Bankole.












Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment