*Owo
babalawo lo ti gba oogun oyun sise naa
Wunmi Agbeluyi |
Gege
bi alaye to te OLAYEMI ONIROYIN lowo, baba to bi Wunmi je babalawo-onisegun to
danto, oun kan naa si loga to ko afesona Wunmi nise isegun tewe-tegbo. Sugbon
awon akoko ti afesona re n kose lowo yii, baba Wunmi ko fowo si ajosepo omo re
pelu omo ikose re rara. Sugbon kete ti baba Wunmi rewaleasa ni ife bere laaarin
awon mejeeji.
Sugbon
nigba to ya, leyin igba ti owo ti wewo daada laaarin Wunmi ati afesona re, ti “nnkan
todun” si ti sele laaarin awon mejeeji ni Wunmi se akiyesi wi pe oyun ti duro
lara oun. Oko afesona, eni to ti mo bi won se n fi eeji kun eeta ba gbe oogun
kan fun Wunmi wi pe ko gbemu. O ni oogun naa yoo mu ki oyun re naa wale
nirowo-rose; niwon igba to ti je wi pe awon mejeeji ko ti setan lati di baba
ati iya omo.
Laiforogun,
leyin ojo meloo kan ti Wunmi ti da nnkan je ninu bere si ni run. Inu naa run
debi wi pe ko loju orun mo, ko le duro, bee si ni ko le bere. Sebi won ni iduro
o si, ibere kosi feni to gbodo mi. Oko afesona re sare gbe lo sile iwosan kan
legbe ile, ile iwosan naa ni won ti fi tipatipa fo oyun inu re naa danu
patapata.
Sugbon
kaka ko san lara iya aje, abo lo tun un fi gbogbo omo inu re bi, eye ba tun un
yilu eye. Inira ati inu rirun ko fi Wunmi sile leyin ti won ba fo oyun inu re
tan. Kaka bee, inira ohun tun goke sii ni. Igba ti agbara osibitu naa ko ka mo
ni won taari re lo si osibitu ijoba ipinle fun itoju to peye. Ile iwosan ijoba
ipinle ti won gbe Wunmi naa lo lo pada dake si.
Gege
bi iwadii OLAYEMI ONIROYIN, omo orukan ni Wunmi, baba ati iya re ti ku. Igba ti oro
naa sele, Wunmi ko jewo ohun ti n se e nipato fun egbon re. Ore Wunmi kan ti n
je Omololu lo sare lo kesi egbon Wunmi nigba ti wahala naa ti gbe won de
osibitu ijoba ipinle.
Ohun
ti a tun gbo ni wi pe oko afesona Wunmi ko jewo fun awon dokita nipa ohun to n
se Wunmi nipato ati orisii ogun to fun un mu.
“Ojulumo kan lo wa fi to mi leti wi pe won ti gbe aburo mi lo si osibitu, ati wi pe, ipo to wa ko dara rara. Mo sara janajana de osibitu, igba ti maa debe, inu inira ni mo ba Wunmi ti n pariwo inu rirun. Bakan naa lo ko lati gba abere atoogun ti awon dokita ni ki won fun un.“Ni akoko ti a fi wa ni osibitu, Wunmi ko jewo wulewule oogun ti afesona re fun wi pe ko mu fun mi. Leyin eyi lo ku, a si lo sin si Ijare. Leyin ti a sin ni asiri oro tu si wa lowo nigba ti awon eniyan tomiwa lati fun mi ni labare,” Funke to je egbon Wunmi se lalaye bee.
Awon eniyan toro naa soju won ni ile iwosan
adani ti oko afesona re koko gbe lo, nibi won ti ba fo oyun naa jade ki won to
gbe lo si osibitu ti ijoba, niwon salaye gbogbo ohun to sele pata fun egbon
Wunmi
Egbon
Wunmi ati awon ebi yoku gbe ejo naa lo siwaju ori ade, Olujare ti Ijare lati ba
won dasi oro naa. Ori ade gba won nimoran lati lo fejo naa sun ni ago olopaa.
Leyin
ifisun yii ni awon olopaa wa mu babalawo ati dokita to ba won fo oyun naa danu,
ti won si lo fi won pamo sinu gbaga.
Nibayii,
awon ebi oloogbe ti n rawo ebe si ijoba, awon alase ati gbogbo eni toro naa kan
lati dide iranlowo ki idajo ododo le waye.
“Abigbeyin ebi wa ni Wunmi, ibanuje nla ni iku re je fun idile wa, a si be awon alase lati je ki idajo ododo sele lori awon asebaje ti won won ran Wunmi nibi ti ko ti setan lati lo,” Funke fi kun oro re bee.
Gege
bi ohun ti a gbo lati Ogbeni Femi Joseph, asoju ile ise olopaa ipinle naa, ni
wi pe, iwadii si n lo lowo lati mo gbogbo wulewule isele naa. Bakan naa ni won
se ileri lati kede ababo won leyin iwadii to gbepon.
0 comments:
Post a Comment