Gomina Aregbesola ti ipinle Osun |
Wahala
idasesile awon dokita ipinle Osun eleyii to ti bere lati odun to koja yii tun
bureke nigba ti Gomina Rauf Aregbesola bere ipolowo igbanisise awon dokita tuntun
lati paaro awon dokita ti won dase sile naa. Awon dokita ti won dase sile lojo
kejidinlogbon osu kesan-an odun to koja yii (28/09/2015)
ni won ti bere si ni leri wi pe, gomina ko
ti mo oloko ti n wa a, a ti wi pe, awon yoo fi ile aye su u ayafi to ba fi eto
awon le awon lowo.
Lori
rugudu yii, egbe awon dokita onimosegun ile yii lapapo, Nigeria Medical Association,
ti gbe atejade kan jade wi pe, dokita kankan ko gbodo gbase lowo Aregbe ayafi
to ba da awon dokita ti won dasesile naa lohun lori eto won ti won on beere
fun.
Ninu
oro ti alaga egbe naa, Nigeria Medical Association, eka ti ipinle Osun, Dr.
Suraj Ogunyemi so, o ni Aregbesola ko mo
iru awon ti n ba tayo.
"Ti
Sango ba n pa araba ti n fa iroko ya, bi tigi nla ko. Gomina ko mo iru awon
eniyan ti n ba tayo. A ma fi ile aye su gomina. Kosi dokita tuntun kankan ti
yoo gbase lowo Aregbe. Dokita to ba se bee, ko ni bo lowo ijiya egbe NMA. Bakan
naa ni ko ni si dokita kankan ti o wa nikale lati seto igbanisise imosegun fun
Aregbe. Ko ba dara ki Aregbsola so ohun to to,” Dokita Ogunyemi se lalaye bee
pelu ohun re ti n lo soke fatafata.
Awon
dokita ti won dase sile yii ni won lo fun idasesile nigba ti gomina ko lati san
oju owo osu won pe losoosu. Won ni gbogbo igba ni gomina n fi obe la owo osu
awon si meji bi igba ti eniyan ja buredi onibeji si meji ogboogba.
"Awon
ti won ba le ni i lokan lati gba ise lowo Aregbe, ki won mo ninu okan won wi
pe, pasan taa fi na iyale, o wa lori aja funyawo," Dokita Ogunyemi fenu
oro re gunle bee.
Olori osise ipinle Osun, Ogbeni Sunday Owoeye ti fi da awon
oniroyin loju wi pe, lotito ni ijoba ipinle Osun n seto lati gba awon dokita
tuntun. Bakan naa lo tun se idaniloju re wi pe, kosi ohun kankan to le da eto
naa duro rara.
0 comments:
Post a Comment