Igbimo
ile ise olopaa ile yii, Police Service Commission, ti koro oju si asa lilo awon
olopaa ti won yan lati maa daabo bo awon eniyan pataki lawujo gege bi eru.
Igbimo ti won gbe kale yii salaye wi pe, asa ki awon eniyan pataki lawujo maa
lo olopaa gege bi omoodo nipa gbigbe baagi dani loju agbo fun baba olowo tabi
ki olopaa maa fe ategun si won lara nita gbangban je abuku nla fun ile ise
olopaa Naijiria.
Alaga
igbimo yii, Oloye Mike Okiro ti se kilokilo wi pe, olopaa ti won ba kefin wi pe
o so ara re di omoodo olowo nipa sisekise ti ko jomo ise re ni yoo je ijiya to
ba ye labe ilana ile ise olopaa.
"Awon
olopaa kii se omoodo tabi eru, osise alaabo niwon lati gbe ofin ro. Ti awon
eniyan pataki ba wa toro olopaa fun aabo emi ati dukia won, kii wa se wi pe bi
ki won so won di omoodo ti o maa ba won gbe igba atagbon dani. Ile ise olopaa
ko ni fara mo iru asa bayii mo,” Oloye Okiro se lalaye bee niluu Abuja.
0 comments:
Post a Comment