Dimeji Bankole |
Enikan
to ti fi igba kan je olori ile igbimo asoju-sofin Abuja, Dimeji Bankole ti fi
da awon ololufe re loju wi pe, oun yoo da ogo egbe PDP to ti n jo ajoreyin pada
nipinle Ogun. Oro yii ni Ogbeni Bankole so nibi ipade kan to se pelu awon alatileyin
re ti won je Dimeji Bankole Movement.
Bakan
naa ni Bankole fi da awon ololufe re loju wi pe, oun ko ti setan lati fi egbe
PDP sile gege bi aheso kan ti n lo wi pe oloselu naa ko ni pe fi egbe alaburada
sile.
“Inu
egbe PDP ni mo si wa ni temi, mi o si ti setan lati fi egbe naa sile. Ni agbara
Olorun, PDP yoo pada sipo re to wa nipinle Ogun," bayii ni Bankole se alaye
naa ni ile re to wa ni agbegbe Onikolobo niluu Abeokuta.
Bankole
kan naa yii lagbo wi pe o lakaka lati je oludije ipo gomina ipinle Ogun labe asia
egbe oselu PDP lodun 2015, sugbon ti ireti re jalule nigba ti Buruji Kashamu fi
gbogbo agbara re ti Gboyega Isiaka leyin.
0 comments:
Post a Comment