Oba Lamidi Adeyemi III |
Awon igbimo lobaloba ipinle Oyo ti je ko ye gbogbo eniyan wi pe, kosi oba kan nipinle Oyo to gba ninu $2.1bn to je owo ti won ya soto lati ra ohun ija ogun eleyii ti Dasuki n pin fun awon kan ti won ni awon oba alaye naa wa nibe.
Oro yii ni Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi III tanna imole si nigba to n gbenu awon lobaloba ipinle Oyo soro nibi ayeye odun marundinlaadota (45) ti baba gori oye.
"Ti a ba n so nipa owo ti ijoba ya soto lati ra awon ohun ija ogun, ko si oba kankan ninu awon ijoba ibile metalelogbon (33) to wa nipinle Oyo to gba iru owo bee," Alaafin tun tesiwaju.
"Ti a ba ri awon oba ti won ba gba lara iru owo bee, won kii se awon oba ipinle Oyo,"Alaafin se lalaye bee.
Ninu oro Oba Lamidi, ori ade tun gbe oriyin fun ijoba Muhammadu Buhari pelu awon eto igbogun ti iwa jegudujera ti ijoba re gunle. Alaafin ni gbagbaagba ni awon ori ade Ipinle oyo wa leyin Buhari bi ike. Bakan naa, Oba Lamidi ni awon ko ni simi lati se atileyin fun ikesejari awon eto isejoba re.
0 comments:
Post a Comment