Oga
agba ileese panapana ti ijoba apapo, Federal Fire Service, eka ti ipinle Eko,
Ogbeni Aderemi Olusola Theophilus ti
sapejuwe ikiyesara gege bi ogun-ajisa lati dena ijamba ina abaadi. Ninu oro re,
eleyii to so lori telifisan ipinle Eko, o ni ona to ya ju lati yago fun ijamba
ina ni ki awon eniyan sora fun awon eroja to le tete gbanaje.
Ogbeni
Aderemi tun so siwaju wi pe, ona lati dena ijamba ina ko yo awon obirin ile
sile nipa akiyesi to peye nigba ti won ba n dana ninu ile. Bakan naa lo tun fi
kun un wi pe, ki awon eniyan maa ri daju wi pe gbogbo ohun elo ile ti n lo
monamona ni won pa nigba ti won ba fe jade. Ko sai gba awon awako oju popona
lamoran lati yago fun iwa gbigbe epo sinu keegi ninu oko. O ni awon nnkan
wonyii le sokunfa ijamba ina ojiji.
Bakan
naa, Ogbeni Aderemi ko sai menu ba ipo
ti awon irinse ile ise panapana ijoba apapo tilu Eko wa.
"Ohun to daju ni wi pe, ise wa ko le rorun lai ni awon irinse igbalode to je ojulowo. Pupo ninu awon irinse wa ti a n lo ni won ti dogbo; gbogbo igba ni won baje nitori igba ti lo lori won. Ko ba dara ti ijoba apapo ba le se iranwo nipase rira awon irinse ati oko tuntun eleyii ti yoo ran wa lowo lati daabo bo dukia ati emi awon ara ilu lapapo," Ogbeni Aderemi fi kun oro re bee.
0 comments:
Post a Comment