Smiley face

Awon agba ti yanju laasigbo to be sile laaarin Olubadan ati Gomina Ajimobi

*Wahala naa sele leyin ti Olubadan fi Ladoja je Osi Olubadan
Gomina Abiola Ajimobi
Ikunsinu lo bere laaarin Olubadan tile Ibadan, Oba Samuel Odulana Odugade ati gomina ipinle Oyo, Abiola Ajimobi nikete ti Olubadan mu igbega ba awon omo oye eleyii ti Senato Rasidi Adewolu Ladoja je okan lara won. Ninu atejade tuntun ti eka ile ise ijoba to n risi ijoba ibile ati oye jije fi sita ni won ti pase fun awon omo oye lati se afihan iwe eri ilera won saaju ki won to gba igbega ninu ilana oye jije naa. Sugbon eyikeyi ninu awon omo ye naa ko se eleyii, oro naa si dun Ajimobi bi Olubadan se tesiwaju ninu iwuye tuntun to waye naa.

Igbega yii lo waye ni akoko poposinsin odun tuntun to wole yii nigba ti won fi Ladoja je Osi Olubadan. Ladoja to ti n je oye Asipa Olubadan tele ni won ja ewe akoko le lori laafin Olubadan nigba ti wo fi n je Osi Olubadan.

Igbega awon oloye, eleyii to n mu won sun mo ipo oba jije lo waye leyin iku awon oloye nla meji kan, Sulaimon Adegboyega Alao Omiyale JP to je Balogun ati  Omowale Kuye to je Otun Olubadan. Awon agba oloye meji yii ni won terigbaso  laaarin ose meta si ara won ninu osu kokanla odun to koja yii.

Iku won lo si mu ki awon aye kan sofo loke eleyii to si gba ki awon omo oye to kangun si ipo naa je awon oye to ba ye. Eleyii gan-an lo sokunfa igbega awon omo oye to waye naa.

Ninu iwuye tuntun to waye ni won ti fi Oloye Saliu A.O. Adetunji  to je Otun Balogun tele je Balogun ile Ibadan; Oloye Lekan Balogun ti gbogbo ilu mo si Osi Olubadan tele gba igbega bo si ipo Otun Olubadan; Oloye Akinloye Owolabi Olakulehin to ti  je Osi Balogun tele ni wo fi je Otun Balogun bayii.

Lara awon oloye to tun gun akaba oye soke ni Oloye Olasogade Olufemi Olaifa, eni to ti n je oye Asipa Balogun tele. Sugbon bayii, o ti bo si ipo oye Osi Balogun ninu igbega awon omo oye to waye naa.

Awon yoku ni Sir Eddy Oduoye Oyewole to je Ekerin Olubadan tele lo ti di Asipa Olubadan bayii. Oloye Tajudeen Abimbola ti wo fi je Ekerin Balogun tele ni won ti fi je Asipa Balogun bayii. Nigba ti Biodun Kola Daisi to je Ekarun-un Olubadan tele tesiwaju nigba ti won jawe Ekerin Olubadan le e lori.

Ninu awon omo oye ti wo duro niwaju Olubadan naa ni Solomom A. Adabale to je Ekarun-un Balogun tele lo ti di Ekerin Balogun leyin ayeye iwuye alarinrin naa.

Ayeye ifinijoye to waye naa lo bi awuyeye to saaju ki eto ifinijoye naa to waye nigba ti ijoba Ipinle Oyo labe oludari eka ile ise ijoba ti n risi awon ijoba ibile ati oye jije, Ogbeni Z. O Jayeola fi sita wi pe ki awon omo oye maa fi iwe eri ilera won sile saaju ki won to jaye oye tuntun le won lori. Ikede tuntun yii ni awon omo oye tako, won ni igbese yii ko si lara ilana ifinijoye ilu Ibadan rara. 

“Ti e ba mo itan Ibadan daada, e ri wi pe iru aba yii sajoji. Emi tile ka iru oro bee si aheso lasan nitori wi pe leta kankan ko de odo mi wi pe mo gbodo fi iwe eri ilera mi han ki n to joye,” Oloye Olufemi Olaifa se alaye naa bee.

Ninu oro Ladoja naa, eleyii to se fun awon oniroyin leyin ayeye naa ninu ile re to wa ni Bodija, o ni oun naa gba wi pe gboyisoyi lasan ni oro naa, ko gbodo je otito.

Sugbon ninu atejade eni ti n se kokari fun Accord Youth Volunteer Network, Asiwaju Adekola Adeoye, so wi pe, edun okan nla ni wi pe gomina Ajimobi le raye lati ma tojubo oro awon omo oye pelu hilahilo ti ijoba re ti da sile ni ipinle Oyo.
“Aimoye awon osise ijoba ati agbasese ni Ajimobi je lowo ti ko ti i san. Kaka ki gomina kojumo awon nnkan wonyii to se koko, isese atodunmodun ni gomina n gbiyanju lati yipada nipase eta inu. To ba je wi pe Ladoja to goke gege bi omo oye lo n ta a lara, ko ba dara ki gomina fi ye gbogbo aye,” Adekola se lalaye bee.

Ifinijoye to waye yii lai tele ase ijoba ipinle Oyo lo da ikunsinu sile laaarin Olubadan ati Ajimobi eleyii to pada sokunfa  bi gomina se pase lojo Monde to koja yii wi pe ki won da awon oloye naa pada seyin ninu igbega oye won to waye. Ase yii ni gomina pa nigba to n fun won ni wakati mejidinlaadota (48hr) lati se bee.  Rugudu to waye yii lo mu awon agba-ma-je-o-baje ti ile Ibadan ti a mo si Ibadan Elders Forum dide lati pana wahala naa ni kiakia. Sebi won ni agba kii wa loja, ki ori omo tuntun o wo.

Ipade lati petu si aawo naa lo waye nile alaga egbe naa, Ambassador Olusola Saanu. Lara awon to peju-pese sibi ipade naa ni Dr. Lekan Are, Oloye Adebayo Akande, Oloye Eddy Oyewole, Ojogbon Femi Lana to je omo Olubadan, Lekan Balogun to je Otun Olubadan ati Gomina Abiola Ajimobi .

Leyin ipade to waye yii ni gomina kede wi pe aawo naa ti pari ati wi pe awon agba ti yanju oro naa patapata. Bakan naa lo tun fi kun un wi pe, awon oloye ti won gbega naa le maa je oye won lo.

“E je ka dupe lowo Olorun wi pe o fi awon agba onilaakaye jininki wa nile Ibadan. Oba wa naa si ti fi apere rere lele gege bi asiwaju rere. Olubadan wa lara awon to ran mi lowo lati de ipo gomina ti mo wa yii. Ninu isele yii, omo iya meji lo n ja, awon agba si ti dasi. Wahala naa si ti tan sibe patapata. Awon iwe eri oye to ye kan ti fi le won lowo naa ni ijoba yoo pada seto re pata fun awon omo oye ti won gbega,” Ajimobi se alaye bayii fun awon oniroyin nikete to jade nibi ipade naa.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment