Mimiko ati Dickson |
Awon
omo egbe oselu APC eka ti ipinle Ondo ti bu enu-ate lu Gomina Olusegun Mimiko
ti awon kan tun pe ni Iroko gege bi asaaju ti ko mo eyi to kan lati muse.
Atejade yii lo jade nigba ti won gburo gomina naa nipinle Bayelsa nibi to ti n
lewaju ipolongo ibo fun gomina Henry Seriake Dickson tipinle naa to je omo egbe
PDP.
"Pelu gbogbo laasigbo ti ipinle Ondo wa,
to je wi pe ilaji ipinle naa lo wa ninu okunkun birimubirimu, ti eto oro aje si
ti di akurete patapata, o je kayeefi wi pe gomina tun le roju-raaye gbe eru
eleru lori nigba ti tie si n wole geerege bi igba ti omin wo yanrin. Awon igba
ati akoko ti gomina n lo loke okun lati gbajumo awon oro ara re nikan ati idile
re ju eyi to n lo lati mu igba derun fun awon ara ilu ti won gbe depo agbara lo."
Ogbeni
Otaloro tun salaye siwaju, " Bi mo se n ba yin soro yii, iye ti awon
ileepo n ta epo pentiro ju iye owo ti ijoba apapo ni ki won maa ta a lo ni
ipinle Ondo. Gbogbo eleyii si ni asiri re ti tu si wa lowo. Mimiko lo se ipade
pelu awon alagbata epo lati se eleyii ni ona
a ti tabuku ijoba apapo nipinle Ondo,” Ogbeni Otaloro fi kun oro re bee.
0 comments:
Post a Comment