Awon
eniyan ti won gbe ni agbegbe ekun Guusu Ekiti gbajo tilu tifon nigba ti
arabirin Biodun Olujimi ti n soju won
nile igbimo asofin agba Abuja si obitibiti ounje wolu l’Ojobo ose to koja yii.
Apo
iresi, ororo ati aimoye awon nnkan ti enu n je ni Senato Olujimi ko
wa lati da awon eniyan lola gege bi ebun odun. Lara awon ebun ti Senato Olujimi ko wa ni awon oko tokunbo bi tuntun mefa eleyii
ti okookan re yoo ma lo si ijoba ibile mefa to gbe ekun naa duro.
Gege
bi oro Senato Olujimi, o ni awon kii se oloselu to je wi pe, akoko idibo lasan
ni won yoju si awon eniyan won nigberiko. Bakan naa lo tun so siwaju ninu abewo
re wi pe, ki awon eniyan lo mokan bale, gbogbo ileri ti awon se pata ni awon
yoo mu wa si imuse.
Sugbon sa, gege bi ero Ogbeni Ayo Oluwaseesin
to je omobibi ipinle Ekiti sugbon to fi ilu Eko se ibujoko salaye wi pe, ko ba
dara ti awon oloselu wa ba le ronu idasile ileese alabode ti awon eniyan ti le
sise. Eleyii ti yoo mu won kuro ninu iponju yato si ounje pinpin nigbogbo igba.
O ni owo ti awon oloselu bi senato n gba lati se itoju ekun ti won soju koja
owo ti won fi n ra iresi ti won pin. O si tun fi kun-un wi pe, yoo dara ti ero
yii ba le ye awon eniyan ki won si jigiri lati beere ojulowo eto won lowo awon
oloselu.
0 comments:
Post a Comment