Smiley face

Awon minisita dide ogun si Lassa Fever

*Ijoba apapo setan lati na N140m lori re
*"Kosi Lassa fever nipinle Oyo" - Ajimobi
Ojogbon Isaac Adewole Alhaji Lai Mohammed
Lori ajakale arun Lassa fever eleyii to ti tan kale de ipinle mewaa lorileede Naijiria, to si ti ran awon eniyan mejilelogoji (42) sorun osan gangan ni ijoba apapo ti setan lati na owo ti apapo re je ogoje milionu owo naira (N140m) lati gbogun ti arun naa.

Lassa fever eleyii ti awon onimo isegun se e lalaye wi pe, eku oloyan repete nigbaaya bi elede kan ni i sokunfa arun naa ni apero pelu awon oniroyin waye lori re niluu Abuja.

Apero eleyii to gunle ona a ti segun Lassa fever ni asewole ni minisita fun eto ilera, Ojogbon Isaac Adewole ati akegbe re to je minisita fun eto iroyin ati asa, Alhaji Lai Mohammed se adari fun.

Ninu ipade naa ni won ti n se alaye awon eto won ati awon igbese tijoba fe gunle fun awon oniroyin. Minisita eto ilera, Ojogbon Adewole ko sai menu ba awon ogun oyinbo ni rira eleyii to le gba emi alaisan la lowo Lassa fever ni kiakia. Alaaji Lai Muhammed naa fi da ara ilu loju wi pe, gbogbo ohun to ba gba nijoba yoo fun-un lati ri daju wi pe, Lassa fever dafiseyin teegun n fiso ni orileede Naijiria.

Wayio, ijoba ipinle Oyo, labe akoso Gomina Isiaka Abiola Ajimobi, ti kede wi pe, ki awon ara ipinle naa lo mokan bale nitori Lassa fever ti pada wole lo raurau ni ipinle naa.

Iberubojo arun Lassa Fever lo be sile nipinle Oyo nigba ti won kefin wi pe arun naa ti fo mo enikan to si je wi pe, abe akiyesi ati itoju awon dokita ni eni naa  wa.

Oludamoran fun gomina ipinle Oyo nipa iroyin, Ogbeni Yomi Layinka fidi re mule wi pe, lotito ni isele naa waye. Sugbon kete ti isele naa sele ni awon dokita alaso funfun ti won wa ni osibitu UCH to kale si Oritamefa niluu Ibadan ti dide lowo kan, ti won si wo alaisan naa lawoye kuro lowo Lassa Fever.

"Minista eto ilera fun ara re ti pe mi lati fi damiloju wi pe kosi Lassa Fever nipinle Oyo mo. Eni ti Lassa fever naa mu ti gbadun.

Gbogbo awon eniyan ti won ni ibapade pelu re ni a si ti se ayewo fun pata. Iwadii si fi ye wa wi pe kosi eyikeyi ninu won to ni arun naa lara," Ogbeni Layinka se alaye naa be.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment