Kayeefi
nla sele l'Ojoru ose to koja yii nigba ti dokita ati awon noosi ti won wa ni
Lagos State University Teaching Hospital to kale s'Ikeja niluu eko feyin rin
nikete ti won gbe alaisan kan wole, eni ti n da eje lati imu re. Apere ti awon
osise ilera naa ri koko ba won leru, eleyii ti won ro wi pe o le je Lassa Fever
lo rolu alaisan naa.
Leyinoreyin,
awon osise ilera naa pada sunmo alaisan naa leyin ti won ti lo dira ni ona ati
dena aisan buruku naa lati bo si ara awon. Awon agba dokita ti won wa nitosi
naa sokale, won si pase wi pe ki won se iwadii ayewo finifini lati mo iru aisan
to n se okunrin alaisan naa gan-an.
Awon
agba dokita naa si tun tenumo wi pe, ki awon osise ilera ye e paya lati se
irawon fun awon alaisan ti won ba gbe wa. Won ni okunrin ti eje n yo nimu re
leje nipase iko tuberculosis eleyii ti n
won lo ti n wu saaju ki won to gbe wa si ile iwosan.
Ninu
oro minisita fun eto ilera, Ojogbon Isaac Adewole, o ni o je ohun to kudiekaato
lati maa ri osise ilera ti n sa seyin fun alaisan. O ni osise to ba se bee yoo
ri pipon oju ijoba. Bakan naa lo tun ro awon eniyan lati maa gbe awon eniyan ti
won ba fura si wi pe o ni aisan yii lo si ile iwosan LUTH nitori wi pe awon
akosemose ti won mojuleja Lassa Fever ti wa nikale lati se iranlowo fun won
alaisan.
0 comments:
Post a Comment