Smiley face

Awon olopaa ilu London ti pada gba Madueke lalejo



Diezani Alison Madueke
Minisita fun epo robi labe isejoba Goodluck Jonathan, Arabirin Diezani Alison Madueke ni won ti kofiri re ni ago awon olopaa ilu London, Charing Cross Police Station, l’Ojobo ose to koja yii. Ifarahan Alison Madueke lati wa dahun awon ibeere kan lo ni i se pelu esun jegudujera ti won fi kan an lodun to koja.


Alison Madueke, eni ti won gbe lori esun jegudujera ti won si pada gba idasile re pelu adehun wi pe ko tun farahan lojo kokanlelogun osu kefa odun to koja. Sugbon to je wi pe ninu osu kewaa ni Alison Madueke to pada ko si panpe awon agbofinro ilu London pelu awon eniyan merin kan ti won fi esun  riba, jegudujera ati sise owo ilu mokumoku kan.

Lara awon esun ti won tun fi kan Alison Madueke ni bi o se fi owo ilu ko opolopo dukia jo niluu London ni oruko awon ebi re kan ati awon alabasise po re.

Ni akoko yii ti awon omo Naijeria n reti ki won taari Alison Madueke siluu Naijeria lati wa foju wina ofin ni awon agbejoro re ati idile re ni obirin naa ni aisan jejere. Won si ro awon eniyan ki won jawo lori oro obirin naa latari ipo ailera re.

Isele to tun tele ni bi agba onise iroyin kan, ogbeni Dele Momodu, se se afihan foto Alison Madueke ninu ipo ailera re lori ayelujara gege bi eni ti aisan jejere n baja lotito. Ogbeni Momodu salaye wi pe, oun ya foto obirin naa ninu ile re niluu London nigba ti oun ba a lalejo lati fi oro wa lenu wo eleyii to dale esun owo tabua ti won lo koje. 

Oniroyin naa se ileri lati se atejade awon alaye Alison Madueke lori esun ti won fi kan naa ninu iwe iroyin re tuntun to fe jade ti won pe ni The Boss. Sugbon ti di akoko yii, iwe iroyin naa ko ti jade. Aitete jade iwe iroyin naa si ti bere si ni ko awon eniyan lominu, eleyii ti won ro wi pe, foto ti n se afihan ailera obirin naa le je iro funfun. Won ni o le je ise owo awon asaraloge onitiata ti won maa n lo ogbon alumonkoroyi lati so omoge darugbo loju gbogbo aye.

OLAYEMI ONIROYIN gbiyanju lati ba ogbeni Dele Momodu soro lori akoko ti iwe iroyin re naa yoo jade, sugbon okunrin naa ko ti fesi ranse pada titi di akoko akojopo iroyin yii.  


Eyi ni awon iroyin to ti jade tele nipa Diezani Alison Madueke:


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment