Dangote ati Gates |
Bill
Gates, eni ogota odun (60yr) to tun je okunrin to lowo ju lagbaye, ti wo ilu
Naijiria lati towo bowe adehun atileyin fun Dangote Fundation lori eto ipase abere
ajesara lati dena arun romolapa-romolese ti a mo si Polio ati awon ogun oyinbo
lati gbogun ti ajakale arun ati kokoro ti n ba ago ara woyaja.
Dangote
Foundation je ajo eleyii ti Alaaji Aliko Dangote, eniyan dudu to lowo ju
lagbaye, dasile lati nawoja iranwo si awujo gege bi oninu-didun-olore.
Ipinle
Kaduna ni won ti gba Ogbeni Gates lalejo nigba ti gomina ipinle naa, Mallam
Nasir El Rufai n ki kaabo si orileede Naijira. Lara awon eniyan pataki ti won
wa nibi eto adehun to waye naa ni gomina Ipinle Sokoto, Alaaji Aminu Tambuwal.
Awon
yoku ni gomina ipinle Borno, Bauchi, Yobe ati Kano. Koda, Emir tiluu Kano,
Sanusi Lamido Sanusi (eni ti won ti yi oruko re pada si Muhammad Sanusi II )
naa wa nikale nigba ti Dangote ati Gates jo n towo bowe adehun naa nile ijoba
ipinle Kaduna.
Gates ni ajosepo oun ati Dangote lati se iranwo ilera to peye
fun awon eniyan to kudiekaato fun lawujo
yoo so eso rere. O si tun dupe lowo awon gomina ati awon eniyan nla ti won pejo
lati wa yesi. Leyin ipade yii ni Dangote pelu Ogbeni Gates gba ile ijoba Abuja
lo lati lo se abewo si Aare Muhammadu Buhari lori iwe adehun kan naa ti won se
lati gbogun ti arun Polio.
0 comments:
Post a Comment