Seriki
n du ipo oba Olubadan
Gbogbo
aye n ki Balogun Olubadan ku oriire
Gomna
ko ti mo ohun ti yoo se lori wahala naa
Aafin Olubadan tile Ibadan |
“Awon idile Seriki lokan bayii lati je Olubadan leyin ipapoda oba to waja. Ti awon igbimo oye ba si n tesiwaju lati maa te wa loju mole nipa fifi eto wa dun wa, kosi ohun to buru ti a ba fi ara wa je Olubadan, eleyii ti a ti setan lati se bee”. Gbolohun yii to jade ninu leta ti baale idile Seriki niluu Ibadan, Oloye Adebayo Oyediji ko si Gomina Abiola Ajimobi leyin ipapoda Oba Samuel Odulana Odugade ti bere si ni da rukerudo sile laaarin igbimo awon oloye.
Oloye
Oyediji, eni odun mokandinlaadorun (89), to tun je onisowo epo robi si ti je ko
ye gbogbo igbimo oloye ilu Ibadan ati awon afobaje wi pe, oun lokan lati je oye
Oba Olubadan gege bi idajo ofin se gbe e kale.
Lojo
Isegun to koja yii (19/01/2016) ni Olubadan, Oba Samuel Odulana Odugade I,
gbera goke aja lo ba awon babanla re leni odun mokanlelogorun (101). Gege bi
ilana oye oba jije niluu Ibadan, oloye to kangun si Olubadan julo ninu ilana
awon agba oye meji, Otun Olubadan ati Balogun Olubadan naa ni yoo bo si ipo
Olubadan gege bi oba.
Eleyii
lo mu opo awon eniyan maa ya lo si ile Balogun Olubadan, Oloye Saliu Adetunji,
to wa ni Popoyemoja lati lo yo fun un gege bi eni to kangun si ipo Olubadan
nikete ti won kede ipapoda Oba Odulana Odugade.
Bi
o tile je wi pe wahala oye jije Seriki eleyii ti won ko faaye gba laaarin awon
igbimo agba oloye ilu Ibadan ti wa nile tele nipa bi Olubadan se ko lati wuye
Seriki tuntun fun eni to kan lati idile ti n je oye naa. Sugbon wahala naa tun
feju nigba ti won tun se igbega awon omo oye mesan-an kan ni ibere odun yii,
eleyii ti Oloye Saliu Adetunji je okan ninu won.
Oye
Balogun Olubadan naa lo si fun ni anfaani lati di eni ti ipo Olubadan kangun si
julo ni akoko yii.
Idile
Seriki gba wi pe, eto ifinijoye to waye naa ko lese nile, nitori wi pe Olubadan
ko lati tele ase ati idajo ile ejo. Eleyii si farahan ninu leta ti idile Seriki
ko si gomina lati ma fi onte lu iru ifinijoye naa nitori wi pe o tako ase ti
ile ejo pa.
Gege
bi alaye won, lati igba ti Oloye Adisa Akinloye, eni to jade laye lodun 2007
leni odun mokanlelaadorun (91), ni Seriki to je keyin ni idile naa. Lati igba
naa ni awon igbimo Olubadan ti ko lati yan Seriki tuntun lati igba naa wa.
Ninu
leta ti Baale idile Seriki niluu Ibadan, Oloye Oyediji, ko eleyii to dale idajo
ati ilana kootu ti ojo kinni osu kejila odun 1989, eleyii to so wi pe, “awon ti
won je Seriki lo kan lati bo si ipo oye Ekerin Balogun ati Ekerin Olubadan. To ba
je wi pe awon Olubadan ati igbimo re ti se ohun to ye lati odun naa, eleyii ti
won ko lati se, awon oloye ti n je Seriki ko ba ti de ipo oba Olubadan tipetipe
saaju ki Oba Samuel Lana to roba je. A ti se suuru fun igba pipe ju, awon
eniyan si ti bere si ni fi oju omugo wo suuru wa laatari didake ti a dake.
“Nibayii
ti a ti ri aridaju labe ofin ati odo awon onimo wi pe, awon idile Seriki lokan
bayii lati je Olubadan leyin ipapoda oba to waja. Ti awon igbimo oye ba si n
tesiwaju lati maa te wa loju mole nipa fifi eto wa dun wa, kosi ohun to buru ti
a ba fi ara wa je Olubadan, eleyii ti a ti setan lati se bee.” Oloye Oyediji ko
sinu leta re bee.
Sugbon
sa, gege bi alaye Oloye Adegboyega Arulogun, eni to ti fi igba kan je komisanna
fun eto iroyin ni ipinle Oyo atijo, to si tun je aromodomo Oloye Gbolagun
Arulogun to je Sariki akoko ti o raye wo inu igbimo Olubadan nigba ti won fi
joye Ekerin so wi pe, babanla oun to je Ekirin nigba naa gba igbega oye de Asipa
ko to sile bora.
Ninu
alaye Oloye Adegboyega Arulogun, o ni oun to le mu Sariki je oye Ekerin eleyii
ti o fun ni anfaani lati wa ninu igbimo Olubadan ni ti agba oloye meji baku
ninu okan ninu awon ilana oye meji to kangun si Olubadan. O ni ti eyi ko ba ti
sele, oye Seriki ko le gberi. Bakan naa lo tun so siwaju wi pe, awon agba oloye
meji to silebora, eleyii to sokunfa igbega awon omo oye to waye, kii se ori
ilana kan naa ni awon oloye meji naa wa, okan je ti Balogun nigba ti ekeji je
Otun, idi niyii ti ko fi si saaye fun Sariki.
Bakan
naa ninu alaye Baale Ekotedo, Oloye Taiwo Ayorinde, o ni Oloye Oyediji ati
idile re kan fe fi oro to wa nile yii da efori sile fun gomina lasan ni.
"Ninu itan Ibadan, nigba iwase, iranse ni Seriki je fun Olubadan ni akoko
ogun. Bawo wa ni iranse yoo se wa je Olubadan? Ko sele ri ninu itan."
Ninu
oro ogbeni Akin Oyedele, amugbalegbe nipa eto iroyin fun Gomina Ajimobi, jeri
wi pe, lotito ni oro naa ti de iwaju ijoba ipinle Oyo. “Gbogbo bi nnkan se n lo
naa lo ye wa. Ilana ati abajade kootu lori oro naa wa lowo wa pelu. Sugbon mo
fi n da yin loju wi pe, Gomina Ajimobi yoo gbe gbogbo igbese to ba ye lori oro
naa,” Ogbeni Oyedele se alaye bee.
0 comments:
Post a Comment