Aare Muhammadu Buhari |
Nibayii,
ijoba apapo, labe akoso Muhammadu Buhari, ti pase wi pe, awon yoo ma ja aadota
naira (N50) lori owo ti enikeni ba gba wole sinu apo ifowopamo banki re. Eto tuntun
yii ni won se gege bi ona lati pawo wole sinu asunwon ijoba apapo. Won ni owokowo
to ba wole si apo ifowopamo onibara banki to ba ti ju egberun kan naira lo (N1k)
ni won yoo ti maa ja aadota naira (N50).
Ko
niise iru ona ti owo naa gba wole, aadota naira ni lati gbon sile lara re, yala
eleyii to wole lati ori ayelujara tabi eyi ti won san wole lori ganta ni banki.
Awon
aadota naira ti won ja lori owo to wole si apo ifowopamo onibara banki yii ni
Nigeria Postal Service yoo ma se kokari fun. Ninu alaye won, won ni aadota owo
naira yii duro fun owo sitampu to n gbe owo naa wole gege bi sitampu ti eniyan
n ra lati fi leta ranse. Won ni bakan naa, awon eniyan yoo ma sanwo sitampu yii
lori awon owo to wole sinu apo ifowopamo won.
Bi
awon owo yii se n wole si apo ifowopamo bee ni aadota naira yoo ma fo yo kuro
ninu re loju-ese.
Leyin
ti Nigeria Postal Service ba gba iru awon owo bayii jo tan lowo awon banki
gbogbo to wa jakejado Naijira, ni won yoo tari ri re si banki apapo CBN to kale
siluu Abuja.
0 comments:
Post a Comment