*O
ni ko daruko awon to ko N1.34 tn je tabi…
Ayodele Fayose |
Gomina
Ayodele Fayose ti ipinle Ekiti ti pe Minisita fun eto iroyin ati asa, Alaaji Lai
Muhammed, nija lati daruko awon
gomina to wa loye nigba kan ri ti won ko tirilionu kan ati bilionu
merinlelogbon (N1.34 tn ) je.
Atejade
yii lo jade lati odo amugbalegbe Fayose nipa oro ti n lo ati iroyin ayelujara,
Ogbeni Lere Olayinka, leyin ti Lai Muhammed so wi pe, ninu awon gomina egbe PDP
ti won kuro loye, meedogun (15) ninu won ati awon eniyan bi marunlelaadota (55)
miiran ni won ko tirilionu kan ati bilionu merinlelogbon (N1.34 tr ) mi bi
kalokalo laaarin odun 2006 si 2013.
“Otito
ni wi pe, egbe All Progressives Congress (APC) labe akoso ijoba apapo ti se ipalara
nla fun eto oro aje ile Naijiria laaarin osu mejo ti won gba ijoba. Eyi ti won
ko ba fi maa wa atunse si awon isoro won, iro ni Lai Muhammed pelu awon akegbe
n kojo lati fi tabuku egbe PDP. Eleyii ti won si n se lati fi bo asise ti won
mole." Fayose
Wayio,
Fayose ti ni ninu ki Lai Muhammed daruko awon gomina naa tabi ko toro aforijin
lowo awon omo Naijiria latari iro bantabanta ti o lese n le to n fon kiri
igboro.
0 comments:
Post a Comment