Smiley face

“Ona ti a gba yanju Ebola ma yato si ti iba Lassa”- Ojogbon Adewole

Ojogbon Isaac Adewole


Ijoba apapo labe akoso Aare Muhammadu Buhari tun ti fi  awon ara ilu lokan bale nipa akitiyan won lati kase arun iba Lassa nile patapata. Oro yii ni Ojogbon Isaac Adewole, Minisita fun eto ilera fi n da awon oniroyin loju nile ijoba apapo Abuja nigba to n soro lojo Wesde to koja yii.


Minisita ni, gbogbo agbara ni awon yoo sa lati ri wi pe arun iba Lassa naa kasa nile ninu odun yii. Bakan naa lo tun so wi pe, ona ti awon gba yanju Ebola ko ni awon yoo gba yanju iba Lassa. "Enikan soso lo gbe Ebola wo orileede Naijiria, sugbon ti Lassa ko ri bee, ajakale arun ni," Ojogbon Adewole fi kun oro re be.

Bakan naa lo tun tenumo wi pe, igba akoko ko ni yii ti iba Lassa yoo ma se ijamba ni orileede yii. Ohun to kan sele ni akoko yii ni wi pe, igba akoko ni yii ti ijoba je ki ara ilu mo nipa ijamba ti iba Lassa n se lawujo wa. Ninu alaye yii naa ni minisita ti fi n da awon eniyan loju wi pe, ijoba ko ni dagunla si isele naa rara. Gbogbo ohun to si ye ni awon ti n musa loogun lati kase iba Lassa nile patapata.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment