Awon Yoruba ni tina ko ba tan laso,
eje ki i tan leekanna. Lose to koja lo loun ni mo n so idi pataki ti a fi gbodo
maa fi o kere tan, ida ogun ninu ogorun (20%) owo ti n wole fun wa saaye oto
gedegede fun ipamo lati ra ojo ola wa sile lowo idaamu airi owo na.
Ka so wi pe egberun lona ogoji (40k)
leyin ri losu. O kere tan, e gbodo maa fi egberun mejo (8k) pamo eleyii ti n se
ida ogun owo osu yin. To ba je wi pe
egberun lona ogorun (100k) leyin n ri, egberun lona ogun (20k) ni owo to kere
ju te e gbodo maa fi sipamo to yato fun ojo ola.
Sebi bi oni seri, ola ko ri bee ni i
mu babalawo maa difa ojoojumo. Awon agba
sibo, won ni atoni lati n pete ola.
Lonii, ma so pataki ati anfaani to romo
gbigbe iru igbese bayii. Se e ranti ohun ti mo so wi pe, ida ogun yii ni owo ti
e koko gbodo fayo ko to di wi pe e gbe ohunkohun se ninu owo naa?
1. Asa fifi iru awon owo bayii pamo le
fun yin ni anfaani lati doga ara yin nipa didi olokoowo tabi alajoni ipin-idokoowo.
Aimoye awon ileese nlanla ni won ta ipindokowo won eleyii ti e le fi iru owo
bee ra fun ifokanbale ojo iwaju. Eleyii to fi je wi pe, ni awon akoko ti ko ni si
agbara lati sise mo, awon owo yin te e fi ra ipindokowo yii nii yoo ma sise fun
yin lo. N maa so nipa ipindokowo lojo iwaju.
2. Eyin ti e ba yo ida ogun ninu ogorun
owo ti n wole fun yin, ti eyi to seku ko ba to gbo bukata yin, ohun ti eleyii n
so fun yin ni wi pe, igbiyanju yin ko ti i to, eni lati wa kun ise owo yin si.
Iru oye yii le ma ye yin ni awon akoko ti e n na gbogbo owo yin tan. Sugbon
kete ti e n ti n yo ida ogun pamo lati fira ojo iwaju yin, oye naa yoo ye yin
ni kiakia.
3. Iru owo bayii, e tun le da lori
okoowo tuntun to yato, eleyii ti o maa pawo wole fun yin. Orisiirisii okoowo lo
wa, eyi toju yin ba da si tabi eleyii te e reni la yin loye nipa re je eyi to
dara julo ti eniyan le kowo le lori.
4. Anfaani mii tun ni wi pe, yoo din
inakuna yin ku. Ti owo ba se po lowo eni bee ni bukata n feju sini. Sugbon awon
bukata kan wa to je bukata anadanu. Awon bukata ti ko ni itunmo gidi si igbe
aye eni. Ti e ba ti tete dogbon sara yo owo yii pamo lati ra ojo ola yin, anfaani
lati na owo lori bukata anadanu ko ni wole nitori e ko ni raaye mowo debe.
Maa duro nibi lose yii.s
0 comments:
Post a Comment