Smiley face

Ayeye odun marunlelogoji lori oye: Alaafin Oyo gbarada!


*Oba Lamidi sodun ola, asa ati ewa ile Yoruba
*Aimoye ero repete lojude Alaafin Oyo
*Akewi ni Alaafin rekoja igbakeji Orisa
Ilu Oyo ko gba obitibiti ero ti won ya saafin Oba Lamidi Adeyemi III, eni ti n yo ayo odun marunlelogoji (45th) lori oye. Ayeye odun marunlelogoji alaafin lori oye yii lo bere niluu London lojo kinni osu kerinla odun to koja yii (1/11/2015). Nigba ti Alaafin wolu Oba Elisabeeti pelu ola, ogo, ewa ati iyi ile Yoruba si aarin awon oyinbo alawo funfun ti gbogbo won si n fi erin ati idunnu pade omo bibi inu Adeyemi Adeniran.

Laraawon ibi ti alaafin de niluu London nigba naa ni Oodu radio ati Ben telifisan to je ile ise agbohunsafefe ti alawo dudu, nibi ti Iku Babayeye ti n so nipa pataki asa ile Yoruba. Bakan naa lo si gba awon omo Naija to wa loke okun niyanju lati ma gbagbe asa won eleyii to je ojulowo ju lo.

Koda, Oosa ilu oyo ja ese idunnu pelu ogbontarigi afeseku bi ojo omo Naijiria, Larry Ekundayo, niluu London.

Leyin eyi ni won lo te faaji sile ninu ile Oba Lamidi to kale si adugbo   awon olola inu London eleyii to wa ni Marlin Statford, 2 Millstone Close, London.

Kabiesi lo igba die niluu London ko to pada wale pelu omo re, Akeem Adeyemi to je okan lara awon omo ile igbimo asoju sofin Abuja.

Ayeye odun marunlelogoji alaafin yii ni won tun gbe dide pelu owo agbara lose to koja nigba ti awon oba alaye kaakiri ile kaaro-o-ji-i-re ti gbe wa n kan saara soba Adeyemi.

Gege bi oro awon Yoruba to wi pe, orisiirisii obe laari lojo iku erin. Eleyii ko yato pelu orisiirisii afihan asa Yoruba ati isese lojulowo to kun ojude Alaafin Oyo.

Bi onibata se n takiti bee ni awon onisango n yo ina lenu. Oloya wa lojude Lamidi pelu aso funfun, ijo Esu ati awon olobatala ko gbeyin rara. Lara awon ti OLAYEMI ONIROYIN tun ri ni awon agba awo ti won joko pelu opon Ifa, bee naa ni awon imule agba naa o gbeyin pelu saki lejika orun won. Gbogbo won ni won pejo lati wa ye Alaafin si, nigba ti Oba Lamidi naa si n sure fun onikaluku won lelegbejegbe.

Gege bi akosile itan ilu Oyo se so, ojo kejidinlogun osu kokanla odun 1970 ni Oba Lamidi de ade oba ilu Oyo nigba ti alase Western Region nigba naa, Colonel Adeyinka Adebayo fi opa ase le e lowo lati maa dari ilu Oyo. Oba Olayiwola, eni odun metadinlogorin (77), ni yoo si je oba eleeketalelogoji (43) ti yoo je Alaafin Oyo-ojo-pa-sekere-omo-Atiba.

Ni odun 1973, Agbaoje akewi ile Yoruba, Olanrewaju Adepoju se apejuwe Lamidi Olayiwola Adeyemi III gege bi akanda ti ko yato si oosa ajiki.
"Talo n pe oba lalase ekeji orisa? Ti won ba n pe oba lalase ekeji orisa, bi oba Lamidi ko. Oosa gan-angan ni Lamidi," Olanrewaju se alaye bee ninu ewi re.

Bakan naa ni akewi tun se apejuwe re gege bi olowo, alaanu ati eni to nife awon eniyan gidigidi.

“Alemu-lera, Lamidi ni o ra oti adugbo yii tan. Ara yiya lo fi n nawo, gbogbo igba ni i foti salejo,” Olanrewaju ke sinu ewi re bee to se fun Alaafin leyin odun keta re lori oye lodun 1973.



Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment