Smiley face

Nipinle Kogi, egbe oselu Labour n gbeja Faleke?

*Ile ejo ni kan bura fun Bello gege bi gomina
*Faleke bo sowo SSS ki won to tu sile lojo Satide
*Taani yoo se igbakeji Bello lojo ketadinlogbon osu yii?
Faleke ati Bello
Gbogbo kirakita egbe oselu Labour Party ti ipinle Kogi lati da eto ibura iyansipo gomina Alhaji Yahaya Bello duro nile ejo ti pada jasi pabo. Ile ejo ti n gbo awuyewuye leyin idibo nipinle Kogi ti da ejo naa nu gege bi ejo ti ko lese n le rara.

Ile ejo yii kan naa ti pase wi pe ki eto ibura iyansipo gomina tesiwaju eleyii ti yoo waye lojo ketadinlogbon osu kinni odun yii (27/01/16) nipinle naa.

Alaga igbimo onidajo, Onidajo Halima Mohammed lo pari idajo re bayii l'Ojobo ose to koja yii nigba to n joko ni Lokoja to wa nipinle Kogi.

Ninu awijare Amofin Reuben Egwuaba to je agbejoro egbe oselu Labour Party, salaye wi pe,  Alhaji Yahaya Bello ko ye leni to ye ki won bura fun gege bi gomina tori wi pe ko ni igbakeji ni awon akoko idibo gomina to waye nipinle naa. Amofin Reuben si ro igbimo onidajo naa lati da eto ibura naa duro eleyii ti won ni yoo waye lojo ketadinlogbon osu yii.

Alhaji Yahaya Bello ni egbe oselu APC ipinle naa fa kale lati ropo Abubakar Audu to jade laye nigba ti eto idibo naa ku die ko kesejari.

A ti igba naa si ni Abiodun Faleke to je igbakeji Abubakar Audu ti ko jale lati je igbakeji Bello ti egbe fa kale gege bi gomina ti won dibo yan.

Bakan naa ni Faleke ti leri wi pe oun ko ni yoju sibi eto ibura iyansipo gomina ti yoo waye ninu osu yii.

Ohun ti Faleke n ja fun ni wi pe, oun Jemiisi Abiodun omo Faleke lo ye ki egbe fa kale gege bi gomina tiluu dibo yan leyin iku Audu to je oga re.

Lori wi pe Faleke ko lati ba Bello se papo ni Amofin Reuben gbe awijare re le lori. Sugbon nigba ti awon igbimo onidajo naa wo o sotun, ti won tun wo oro naa sosi pelu ohun ti iwe ofin so, won ni ejo ti egbe oselu Labour naa gbe wa ko lese nile rara. Won si tun pase wi pe ki ibura iyansipo Bello si wa sibe gege bi won ti kowe re kale.     




Wayio, lojo Satide to koja ni ariwo gba igboro ilu Lokoja kan nigba ti okiki kan wi pe awon osise alaabo SSS ti gbe Faleke si ahamo niluu Abuja. Faleke ati Duro Meseko to je adari ipolongo ibo fun Audu to doloogbe ni awon osise SSS niluu Abuja fiwe pe.

Sugbon ijoloju lo je nigba ti awon osise alaabo naa pada fi Faleke ati Meseko si ahamo fun awon akoko kan.
Bi o tile je wi pe won ti pada fi won sile sugbon titi di akoko yii, awon osise alaabo naa ko lati so idi pataki ti won fi gbe Faleke si ahamo.

Sugbon aheso to n lo nigboro ilu Lokoja ni wi pe, Bello to je gomina ti won dibo yan lo wa nidii oro naa. Sebi ti ko ba nidii, obirin kii je Kumolu.

Ni kete ti oro yii n ja rainrain nile ni Bello naa ti fesi wi pe, oun ko mo ohunkohun nipa oro naa rara. Oro yii lo so nigba ti Ogbeni Jude Salau to je agbenuso re nipa eto iroyin ba awon oniroyin so ni Lokoja to je olu ilu Kogi.
"Ki nnkan le daa lemi wa fun. Gbogbo akitiyan ni mo si n se lati ri wi pe aawo to wa ninu egbe wa naa pada niyanju patapata. Emi ko ni mo ni ki won gbe Faleke si ahamo awon osise alaabo SSS," Bello salaye tie bee

Sugbon sa, nibayii ti ile ejo ti pase wi pe ki eto ibura iyansipo naa tesiwaju lojo ketadinlogbon osu yii, ti Falake naa ba si ko lati yoju gege bi ileri re, kini yoo pada je ipin Faleke?

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment