Smiley face

Fayose ṣeleri itẹsiwaju rẹ gẹgẹ bi alatako iṣejọba Buhari



Fayose ṣe abẹwo si ipinlẹ Ọsun lori isọkan ọmọ Oduduwa
“Mi o yan Arẹgbesọla gẹgẹ bi ẹlẹbẹ si Buhari”- Fayose
Fayose ati Aregbesola
Lọjọ Isẹgun to kọja yii ni gomina ipinlẹ Ekiti, Ayodele Peter Fayose, ọmọ ẹgbẹ PDP, wọlu Oṣogbo-oroki-ọmọ-asala lati ba gomina Aregbesola to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lalejo.

Ikede abẹwo Fayose si ipinle Ọsun to ti kọkọ saaju tẹlẹ ti bi aimọye awuyewuye silẹ nigboro. Eleyii ti awọn ahesọ ọrọ ti wọn ọn so naa ni wi pe, Fayose fẹ yan Aregbesola gẹgẹ bi ẹlẹbẹ si Aare Buhari.


Awọn ahesọ ọrọ ti n lọ yii ni gomina Fayose sọ wi pe oun ti rika lori ẹrọ ayelujara, ero rẹ lori aheso naa lo si fi bẹrẹ alaye rẹ nile ijọba ipinlẹ Ọsun.


“Emi o wa sibi nipa gẹgẹ bi aheso ti wọn fọn kiri aye. Bakan naa ni mi o si wa lati wa fi ẹgbẹ PDP silẹ bọ sinu ẹgbẹ mii. Mi o le fi ẹgbẹ PDP silẹ nitori ẹgbẹ kankan laelale; apaadi to sojude ogiri, togiri ni i e. Igba akọkọ ni yii ti n ma ṣe abẹwo si ipinlẹ ti ẹgbẹ APC n dari gẹgẹ bi gomina. Emi o wa si Oṣogbo nitori ki Aregbesola le ba mi bẹ aarẹ gẹgẹ bi ohun ti awọn kan sọ kiri. Ọmọ Yoruba ni gbogbo wa. Omi si loselu, ibi o ba si wu omi lo le san gba,” Fayose tun tesiwaju ninu ọrọ rẹ.



"Mo ni igbagbọ gidigidi ninu iran Yoruba, iran Yoruba lo si saaju ipo gomina. Igba diẹ ni ipo gomina, ti ipo ba tan, Yoruba gẹgẹ bi iran kan ṣoṣo ni yoo sẹku. A ni lati kiyesara lonii nitori ọla. Mo wa nibi lonii fun iṣọkan ọmọ Yoruba eleyii to ṣe pataki si Oduduwa to jẹ baba gbogbo wa."


Bi Fayose ṣe n ba ọrọ rẹ lọ bẹẹ ni awọn ọtọkulu oloṣelu ti won wa nikalẹ si n patẹwọ fun un nipa awọn ọrọ akin ati iwuri ti n jade lẹnu rẹ. Eleyii to se afihan rẹ gẹgẹ bi ọmọ Oduduwa rere ati ẹni to n gbero iṣokan fun iran Yoruba lapapọ. Fayose tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ.


“Inu ẹgbẹ PDP ni mo wa, nibi ti n ti ma tẹsiwaju ipa mi  gẹgẹ bi alatako. Nitori lai si alatako, ijọba taani-yoo-mumi ni awon to wa nijọba yoo ma dalara. Gbogbo awọn ti won si n ṣe agbatẹru iṣejọba taani-yoo-mumi ninu iṣejọba awaarawa ni won yoo pada kabamọ nigbẹyin ọrọ," gomina ipinlẹ Ekiti ṣe e lalaye bẹẹ.


Fayose ko sai tun gba ijọba apapọ niyanju lati lo anfaani adiku to deba iye owo ti won ta epo rọbi lagbaye, eleyii to ti n se akoba fun eto ọrọ aje wa, lati boju wo awon ona  mii ti owo tun le fi wọle si asunwon ijọba.
Eleyii ti ko fi ni jẹ wi pe, epo rọbi nikan ni yoo jẹ larija orisun ipawo-wọle fun ilẹ wa.

Aregbesola nigba ti o n fesi le ọrọ Fayose, o gbe oriyin kabiti fun gomina Ekiti fun emi ifẹ ati ifọmọniyan se eleyii to fi han. Bakan naa ni gomina Aregbe tun fi kun un wi pe, ko ba dara ti awọn ijọba ipinlẹ naa ba le fimọ sọkan nipa eto ọrọ aje eleyii to le mu ìṣẹ́ ati ìyà kuro lawujọ wa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment